Iyalenu loro gendekunrin kan ti won
poruko e ni Okwudili Okoro, ti won lomo bibi ipinle Ebonyi nile Ibo ni si n je
fawon eeyan to gbo nipa bo se sa egbon e, atiyawo egbon e pa lose to lo lohun
si n je fun won, ko da a, tawon kan tun un gbe e sepe titi dasiko yi.
Okwudili |
Ojo Abameta Satide to koja lo lohun
la gbo pe Okwudili kuro nile e to wa ladugbo Salon niluu Abeokuta, to si gba
ile egbon e to wa ni Ijako lo pelu ore e kan ti won pe ni Kenneth lati loo da
won loro.
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo
se so, won ni ni nnkan bi odun merin seyin ni egbon Okwudili, iyen Azuibike lo
si abule won nipinle Ebonyi lati loo muu wa si ipinle Eko, ko ba a le ko nise,
koun naa si le deni to n da duro laaye ara e.
A gbo pe ileri ti Azuibike se fun
aburo e, Okwudili ni pe to ba farabale ko ise naa, to si mon on daadaa, oun yoo
fun lowo ti yoo fi bere okoowo ti e, koun naa si le maa ri owo ti e.
Odun meta gbako la gbo pe Okwudili
fi ko ise karakata lodo egbon e, Azuibike to si ti gba aaye. Leyin to gbaaye
tan la gbo pe nnkan yi pada fun Azuibike, to je pe se lo n je gbese lawon ibi
to ti n ra oja.
Gbogbo bi won se ni Okwudili n da
egbon Azuibike laamu pe ko foun lowo toun yoo fi si soobu toun ni won so pe
Azuibike ni ko si ni suuru foun, sugbon to so pe iro lo n pa foun, ko fe e foun
lowo naa ni.
Won ni losan ojo kan ni Okwudili lo
sodo ore e kan to n je Kenneth lati loo foro naa to o leti, tiyen si gba a
lamoran pe ko loo hale mo, lai mo pe oro naa yoo buu lowo.
Lojo Satide tisele naa sele, a gbo
pe Kenneth lo mu Okwudili lo sibi to ti ra ada tuntun, to si tun lo pon on lodo
awon to n pon ada. Ki won to o gba Ijako lo ninnkan bi aago meje irole.
Nigba ti won baa de ile egbon e,
asiko ti won n jeun lowo ni. Kani Azuibike mo pe ise ibi ni aburo e fe e wa se,
o seese ko ti tetebranse pe.awon araadugbo lati wa gba a sile.
Lojiji la gbo pe Okwudili ati
Kenneth bere sii fi ada sa egbon e, atiyawo egbon.e, Jacinta Okoro titi ti won
fi ku. Bi won se rii pe awon meejeji ti ku ni won ba ese won soro, sugbon tawon
to n gbo ariwo ninu ile tete lo lati loo wo nkan to n sele.
Iyalenu lo je pe nigba ti won maa fi
wole, inu agbara eje ni won ti ri Azuibike ati iyawo e, Jacinta, ati pe se la
tun gbo pe Okwudili n tu inu ile wo bo ya oun le ri owo toun yoo ko, ko to o di
pe awon araadugbo mu.
Lesekese la gbo pe awon eeyan naa ti
loo fa a le awon olopaa Ota lowo. Awon olopaa naa la gbo pe won gbe oku
toko-taya naa lo si.mosuari Sango.
Nigba yo n jeri oro.naa, Ahmed
Iliyasu so pe looto ni, ati pe oun ti tare sodo ajo SARS to wa ni Magbon lati
sewadi e daadaa, kimwon si mu Kenneth to salo, ki won le tete foju won bale
ejo.
No comments:
Post a Comment