Nitori Amosun: Won sun ayeye igbade Olota siwaju - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, April 18, 2018

Nitori Amosun: Won sun ayeye igbade Olota siwaju

Igbimo ati isakoso ti won gbe kale fun ayeye igbade Olota tiluu Ota tuntun, iyen Adeyemi AbdulKabir Obalanlege ti kede sita pe awon ti sun ojo ayeye igbade Kabiyesi tuntun naa siwaju di ojo kewaa osu karun un to m bo.

Kii se pe awon igbimo naa deede sun ojo ayeye ti won ti fi sojo kerindinlogbon osu yi, iyen ojo Tosde ose to m bo siwaju, bi ko se ba a se gbo ti won so pe Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ko le ri aaye lojo naa.

AWIKONKO gbo pe, won ko fe e gbe ade le Oba Obalanlege lori, ki won si tun fun un ni opa ati iwe ase lai je pe Gomina Amosun wa lori ijokoo lojo naa.

Nigba to n kede sisun ojo naa siwaju fawon oniroyin niluu Ado/Odo Ota, alaga igbimo ayeye naa, Seneto Kamorudeen Odunsi so pe awon fe e ki Gomina Amosun wa nibi ayeye lojo naa.

O ni ko nii bu iyi kun Kabiyesi tuntun naa, ko je pe asoju Gomina lo maa gbe ade le Obalanlege to tun je asiwaju awon Oba niluu Ado/Odo, eyi gan an lo fa tawon fi pinu lati sun ojo naa siwaju.

Alaga naa tun je ko di mimo pe bawon tun se pinu lati sun ojo naa siwaju yoo fun awon igbimo isakoso ayeye naa lanfaani lati tubo gbaradi lara-otun daadaa, ki eto naa le lo bo se ye ko lo.

Odunsi tesiwaju pe ojo karun osu karun ni eto ayeye igbade naa yoo bere ni pereu, nibi ti Ojogbon Olanrewaju Fagbohun ti ileewe fasiti ipinle Eko yoo ti soro lori koko oro ti won pe ni "Ile Awori to koja aala: Ojuse awon alabojuto oro oye jije" (Aworiland Beyond Borders: Role of Traditional Institution).

Nigba to n rawo ebe sawon araalu lati tele ikilo nitori pe won yoo gbe Oro lati ale ojo kewaa si ojo ketala.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI