Laaro ojo Tosde ose to koja yi ni
ile ejo koko koko tu igbeyawo ologun odun to wa laarin iyale ile kan, Arabinrin
Abiola Adetunji ati oko e, Ogbeni Kehinde Adetunji ka leyin osu meji ti ejo naa
ti dele ejo.
Ohun ta a gbo ni pe iyale ile eni
odun mokandinlogoji (39) lo mu ejo oko e lo sile ejo ninu osu keji odun yi naa
pe ki won gba oun lowo oko oun to fe e fi oorun igbo pa oun atawon omo meji
toun bi fun un sinu ile.
A gbo pe gbara ti Abiola Adetunji ti
ro ejo nile ejo lojo kerindinlogun ni awon onidajo meji to n gbo ejo awon eeyan
nile ejo naa, iyen Oloye Akande O. O. Ati Onarebu Arabinrin Majekodunmi H. I.
ti fise ranse si baale ile naa pe ko yoju sawon lojo kokanlelogun osu keji naa
lati wa a so tenu e.
Nigba to di ojo naa la gbo pe
Kehinde ko yoju, eyi lo mu ki won tun fise ranse sii pe ko yoju sawon lojo
ketala osu keta to koja yi, pe o see se ko je pe iro n iyawo e, Abiola wa a pa
mo on nile ejo, ko si tete wa a so tenu e, sugbon ta a tun gbo pe ko yoju.
AWIKONKO gbo nnkan tawon onidajo
mejeeji tun so lojo naa ninu iwe ti won tun ko ranse si Kehinde ni pe bi ko ba
yoju sawon lojo karun un osu yi, iyen lojo Tosde to koja yi, awon yoo tu
igbeyawo naa ka.
Abiola nigba to n fi bibeli bura
niwaju awon onidajo mejeeji so pe "Oko mi fe e fi oorun igbo pa emi atawon
omo sinu ile, ko si nii toju wa tabi ko fun wa lowo ounje. Emi nikan ni mo n da
gbo bukata ninu ile, ti ko tun ni mo fun mi.
"Danfo lo n wa tele, sugbon
tirela lo n wa bayii. To ba a ti fe e mu igbo e, se lo maa ti gbogbo ferese ati
ilekun, to ma maa fa a bi eni ti aye n se. Ti m ba soro, alupa maku lo maa n fi
mi se. Opo igba ni mo ti loo fejo e sun awon ebi e, sugbon ti ko gbo si won
lenu ti won ba pe e lati ba a soro.
"Igba to si mi ni mo ko awon
omo mi jade kuro nile ta n gbe ni Oke-Ijemo, ti mo si loo gba ile si adugbo
Ijaye. Titi di bi mo ti n soro yi, ko tii yoju, tabi ko pe mi lati beere awon
omo.
Abiola to ni oti elerindodo ati omi
loun n ta tun je ka mo pe omo meji loun bi fun Kehinde, o ni Segun Adetunji to
je omodun mokandinlogun (19) ati Oluwasegun Adetunji toun je omodun
metadinlogun (17) lawon omo toun bi, ti ko si mo bi won se n lo nileewe.
Oloye Akande nigba tonn gbe idajo
kale so pe awon ti gbiyanju gbogbo agbara won lati ma je ki igbeyawo naa daru,
sugbon tawon rii pe Kehinde nife iyawo e mo, eyi to fa a ti ko fi yoju lati wa
a so tenu.
O loun pa a lase pelu ofin ile ejo
koko koko naa pe ki igbeyawo ologun odun naa tuka lesekese. Bee lo so pe tojo
tiyawo naa lo lase lati fe enikeni to ba wu won lai si wahala.
Bakan naa lo so pe ki Abiola maa ko
awon omo naa si odo e gege bo se n fe, ati pe igba to ba wun baba awon omo naa
lo le wa a wo won, ti ko si gbodo ko won pamo fun. O tun pa a lase pe Kehinde
ko gbodo de soobu Abiola lati loo fa wahala mo.
No comments:
Post a Comment