Ife awon eeyan mi lo je mi logun – Onarebu Bankole - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 26, 2018

Ife awon eeyan mi lo je mi logun – Onarebu Bankole

Okan lara awon omo ile igbimo asofin nile igbimo asofin nipinle Ogun, Onarebu Olusola Aknbi Bankole to n soju ekun Ado-Odo Ota I ti so pe ife awon eeyan e lo je oun logun pupo, eyi to mu koun tun fe e lo soju won nile igbimo asofin agba niluu Abuja.

Onarebu Bankole lo soro yi lakoko to n b’AWIKONKO soro lai pe yi, O ni ko si nnkan to je oun logun ju nigbesi oun, bi ko se ilosiwaju ati idagbasoke awon eeyan toun n soju nile igbimo asofin ipinle Ogun.

Bi e ba n so nipa awon omo ile igbimo asofin nipinle Ogun to ti mu idagbasoke ba agbegbe e, ko si bi e o se ka marun un, ti e ko nii daruko Onarebu Olusola Bankole, eyi to mu kawon eeyan ekun Ado-Odo Ota I tun so pe oun lawon fe ko wa lo soju awon nile igbimo asofin agba niluu Abuja lodun 2019.

Bankole je ko di mi mo pe egbe oselu APC loun fe e gba jade lati dupo naa lodun 2019, toun si mo pea won eeyan yoo gbaruku ti oun lakoko idibo, ti won yoo si fi ibo won gbe oun wole.

Bee lo so ninu oro e pe awon ise akanse manigbagbe loun ti se tie kun oun latigba toun ti n soju won, topo awon toun n soju si le jerii si awon ise akanse naa, toun tun ti peluu gbe aba ilosiwaju nipa agbegbe oun dide nile igbimo asofin naa.

O so pe lati odun meje seyin loun ti wa nile igbimo asofin ipinle Ogun to fikale si Oke-Mosan niluu Abeokuta, toun si n soju won daadaa, ati pe kani oun ko mu awon ileri oun toun se lakoko se ni, awon eeyan oun ko tun ni so pe koun pada lo leekeji.

Bakan naa lo gbawon araalu lamoran pe ki won tete lo o gba kaadi idibo alalope, iyen Permanent Voter Card won ki akoko to o lo, nitori pe asiko ipolongo eto idibo ti n sun mo etile.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI