E ba mi be oko mi pe ko tu mi sile ninu aisan to gbe si mi lara - Motunrayo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 23, 2018

E ba mi be oko mi pe ko tu mi sile ninu aisan to gbe si mi lara - Motunrayo

Ko da, beeyan ba je ori ahun, to ba wa nibi ti iyale ile kan to ti bimo meta nile oko e se n soro oko e ni ileejo koko koko to wa ni Ake niluu Abeokuta lojo Monde to koja yi, omije yoo fe e le jabo loju onitohun pelu b'obinrin naa se n soro peluu ibanuje okan.


Ko si nnkan meji to je ki iyaale ile naa, Arabinrin Motunrayo Matthew to so pe ogun odun re toun ati oko oun ti fera bi ko se ti aisan olojo pipe to wa lara e, ko da to da bi eni pe aarun kogboogun, iyen eedi (AIDS) lo n ba a finra, nitori to ti fe e gbe tan mo ori iduro.

Nigba to m soro, Motunrayo so pe latigba ti oko oun, Daniel Matthew ti fe iyawo meji le oun ni aisan naa ti bere, to si je pe gbogbo ibi toun n de ni won n so pe ko seni meji to n se oun, bi ko se baba awon omo oun.

Obinrin naa je ko di mi mo pe owo wa lowo oko oun daadaa bii sekere ko too di pe o fe awon iyawo meji naa le oun, bee lo so pe oko oun ni ile (land) ati moto meta, sugbon ko pe to fe awon iyawo naa ni nnkan bere sii dojuru fun de bi pe o bere sii ta awon moto e ni kookan.

Ninu oro e, o so pe "Iyawo meji ni Daniel ti fe le mi, ko too fe won, owo wa lowo e daadaa, o ti rale peluu moto meta. Igba to fe awon iyawo yen lo di pe nnkan bere si i dojuru fun un, ti ko si nnkan kan lowo e mo. Igba yen lo bere si i ta moto atawon nnkan ini e mi-in to ni, to di pe ko si nnkan kan lowo e mo.

"Sadede ni oko mi so pe emi ni mo n se oun ti gbogbo nnkan fi dojuru. O maa maa ji emi atawon omo mi laarin oru, aa waa maa so pe won ni obinrin kan n finu ba oun ja ninu awon iyawo oun, pe won ni obinrin naa lo je ki nnkan oun dojuru. Mo de maa n so fun un pe emi o se nnkan kan fun un, mi o ba a ja rara pe o feyawo le mi, sugbon nise loko mi maa n so pe ninu ki oun gbe aare le obinrin naa lowo, tabi koun ya a ni were, okan gbodo sele nibe.

‘’Ko pe sigba to soro naa ni aare de si mi lara, aare buruku naa to je pe won ko ri nnkan to n se mi ni, mo kan sa n gbe ni, mo tun n funfun ni gbogbo ara. Gbogbo owo ni mo fi ya Xray(Aworan inu ara) tan, won ko ri nnkan to n se mi, mi o de yee gbe, bee ni gbogbo ara mi aa wuwo bii pe won di eru le mi lara.

"Di bi mo se n soro yii, mi o ti i gbadun, aare yen ko lo. Oja ni mo n ta tele, mi o le ta nnkan kan mo latigba ti aare yii ti de. E ba mi be Daniel ko tu mi sile, emi ko ni mo n se e. Mo de tun fe ke e ba mi pase fun un ko maa waa sanwo ileewe awon omo e, ko de maa fun won lounje, ohun ti mo ba wa niyen."

Nigba to n tako awon esun tiyawo e fi kan an, Ogbeni Matthew Daniel to loun maa n bawon to n se buredi ko buredi lo fawon to maa ta so pe iro niyawo oun n pa nitori pe ori aisan to wa lara e loun ta moto atawon dukia oun le lati le je ko gbadun.

Baale ile naa ni looto loun fe iyawo meji, sugbon ko nii se pelu aisan to n se, toun ko si mo ile babalawo depodepo pe oun yoo fi aisan sara iyawo to bimo meta foun.

"Igba kan wa to saisan nla bee, o ni inu ile ta a n gbe yen ni ko daa, ki n je ka kuro nibe. Mi o ba a jiyan, mo gbe moto kan ta ka le ba a rowo gbale, bi mo se ta moto naa tan la kuro ninu ile yen. A tun de ibo mi-in to ni ka loo gba, o tun saisan mi in. Mo  ti fe awon iyawo meji yen le e nigba yen ti kaluku won n gbe lotooto. Mo kan saa ri i pe o yiwa pada si mi ni, ko se bo se maa n se si mi tele mo.

"Igba to di odun 2017 to koja yii lo keru jade nile, to loo gbale sibomin, o ni nitori aisan to n se oun naa ni. Emi o faisan se o, mi o si mo nnkankan nipa ara e ti ko ya."

Nigba tawon naa n soro, Aare kootu naa, Oloye Akande O. O ati igbakeji e, Onarebu Majekodunmi H. I so pe iwa ti Baale ile naa hu ku die kaato nitori pe awon iyawo to fe ko ni ko pa Iyaale ile e to bimo meta fun un ti.

Won ni kawon to le so ohunkohun le oro naa, a fi kawon mejeeji mu awon eeyan won wa lati wa jeri soro won lojo kewaa osu karun, bee ni won gba Iyaale ile naa lamoran pe ko mojuto ara e daadaa lai duro de oko e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI