Dokito Smile Fee Gbarada Niluu Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 14, 2018

Dokito Smile Fee Gbarada Niluu Abeokuta

Gbogbo eto lo ti n lo lowo fun ti ipalemo eto alaragbayida kan ti gbajugbaja apanilerin in nni, Ogbeni Ogunmuyiwa Oluwapamilerinayo tawon eeyan mo si Dokita Apanilerin, iyen Dr. Smile gbe kale lodoodun, to pe ni Dokita Apanilerin Ti Ko Wopo (Dr. Smile Unusual).

Dr. Smile
Eto naa to je eleekerin iru e la gbo pe ojo Isegun Tusde, ojo kinni osu karun un to n bo lo maa waye ni gbongan ile ikawe Aare orileede yi tele, iyen Obasanjo Presidential Library, OOPL to wa ni NNPC, Abeokuta.

Fawon to ba ti n kopa nibi eto naa latigba ti won ti bere e, won yoo mo pe eto naa koja afenuso nitori pe lati ibere eto naa titi dopin lawon eeyan yoo fi je igbadun ara won, ko da tawon min in maa n gbagbe ara won sori ijokoo bii pe ko si maa tesiwaju ni.

Gege b'AWIKONKO se gbo, eto todun yi ti won pe ni Season 4 la gbo pe opo awon apanilerin kaakiri orileede ni won ti n gbaradi lati wa efe ati awada igbalode ti won yoo fi dawon eeyan laraya lojo naa.

Kii se pe won deede gbe eto naa kale lati fi pawo, sugbon ohun ta a gbo ni pe opo awon eeyan lonii lo je pe ojoojumo ni won n fa oju ro, ti won a maa fun oju po lai ba eeyan ja, eyi lo fa a ti Ogbeni Oluwapamilerinayo fi wo o pe ona wo loun le gba lati mu kawon eeyan maa rerin ni gbogbo igba, to si rii pe ko tii seni to n se iru eto be e.

Bo tile je pe kii se eto Dr. Smile Unusual ni akoko, nitori tawon iru eto bee po kaakiri, sugbon kii se toro asodun pe iwaju ni eto Dr. Smile Unusual wa laarin awon iru eto bee, tawon eeyan kaakiri si n jeri sii.

AWIKONKO gbo pe ona ara oto ni ayeye todun yi fe e gba sele latari awon eto alarambara ti won ti la kale fun ojo naa, nitori pe opo awon eeyan jannkan-jannkan lawujo kaakiri orileede yi, to fi mo awon to wa loke okun ni won ti n gbaradi lati kopa.

Yato sawon gbajugbaja apanilerin kaakiri orileede Naijiria to n bo lojo naa, bee lawon olorin taka sufe (hiphop) naa ko nii gbeyin lojo naa.

Lara awon ilumooka apanilerin to n bo lojo naa ni: Teju Babyface; Gbenga Adeyinka; Seyi Law; Honey Tongue; SACO; Woli Arole; Woli Agba; MC Bishop; MC Bassy; Dr Frick.

Awon min in ni: ATM; MC Password; Chris Lecturer; Bash; MC Rapingsdaddy; Still Ringing atawon min in bee lo. 

Nipa ti owo iwole, iyen tikeeti, AWIKONKO gbo pe egberun meji (2000) naira ni fawon mekunnu (Regular), egberun marun un (5000) ni fawon olowo, nigba ti egberun lona ogorun (100,000) ni tawon to fee jokoo lori aga eeyan mejo (Table of 8).

Fun alaye lekunrere, e pe; 07055247474

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI