Awon odo Naijiria yari mo Buhari lowo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, April 20, 2018

Awon odo Naijiria yari mo Buhari lowo

Titi di bi e ti n ka iroyin yi lawon odo orileede Naijiria si fi n fehonu won han lori oro abuku ti Aare Muhammadu Buhari so si won pe ole (lazy) ni won, won ko fe ise e se, ati pe nnkan ofe ni won n wa kaakiri.

Lojo Wesde to koja yi ni Muhammadu Buhari soro naa jade lakoko to n soro niluu oyinbo pe “A ni opo awon tojo ori won kere; iye wa lorileede yi bi a ba ni ka foju wo, a ti wo ogojo milionu (180milion).

“Awon to ida ogota (60%) ninu iye ta a je ni ojo ori won ko ju ogbon lo. Opo ninu won ni won ko gba ile eko koja, ti won si n so pe orileede Naijiria je orileede to n se epo robi (oil) jade, fun idi eyi awon ni lati jokoo feyinti lai sise, kawon si maa gba ile ofe, eto ilera ofe ati eko ofe.”

Bi oro yi se jade sita, ti fonran (fidio) e naa tun jade tele e lawon odo ti gba ori ero ayelujara lo lati loo tako oro Buhari pe ko gbenu e sohun, ko ye e so isokuso nipa orileede yi, paapaa awon odo kaakiri agbaye nitori pe se lo n ba oruko orileede to n soju e je, to si ro pe oro gidi loun n so.

Bo tile je pe Ogbeni Femi Adesina to je agbenuso fun Aare Muhammadu Buhari tako bawon odo naa se n fesun kan Buhari lori oro to so, o ni kii se nnkan ti oro ti Buhari so tunmo si ni ona ti won gbe e gba, sibe awon odo so pe ise e lo n se e, ati pe owo osu e to n gba lodo Buhari lo muu maa gbe oga e leyin.

Bawon kan se n so pe inu awon dun lati je okan lara awon odo alapasise ti Buhari n so nitori pe pelu opolopo odun tawon lo nile eko, tawon ko si fi ri ise se labe ijobaa ati aladani, sibe awon ko duro lati maa fese gba ile kaakiri, tawon si n wa ona tawon yoo maa gba ri owo.

Kii se asodun pe kaakiri agbaye, awon omo orileede Naijiria lo po ju lawon orileede min in bii Europe, Asia atawon min in to je pe tosan toru ni won fi n wa ona bi won yoo se jeun, ti won n ba ise aje kiri.

Agbenuso fun ijoba ipinle Ekiti, Ogbeni Lere Olayinka nigba to n fehonu han so pe ki Aare Buhari ye e so pe ole alapamasise loun nitori pe bo tile je pe awon obi oun ko ri owo ran oun koja ile eko girama lo, sibe oun tiraka lati lo ko ise awon to n ran bata fun odun meje, toun tun se ise muyiwa, iyen ise omoodo ni ofiisi fun odun merin gbako nitori koun le ri owo fi ran ara oun lo sile eko giga fasiti.

Olayinka so pe oun ko tun duro nibe, oun tun tiraka lati ka iwe siwaju sii, toun si je agbenuso fun gomina ipinle oun lonii, tawon eeyan tun n kan saara soun pelu boun se je odo.

Gbadura Oluwasola so pe kii Aare Buhari ye e so isokuso nipa awon odo, ko si ye e ba oruko orileede yi je kaakiri agbaye.

Awon kan tile so pe akoba nla ni Buhari je fun orileede Naijiria lasiko ta a wa yi pelu bo se n ba oruko orileede yi je kaakiri agbaye ni gbogbo igba to ba rin irin ajo kan jade.








No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI