Airise se lo je ki n gbe igba e - Christian
Yoruba
bo won ni oruko n ro ni, sugbon se loro naa yi pada fun gendekunrin omo Yibo
kan, Christian Ifedebo lose to lo lohun nigba towo olopaa te e pelu paali
egbogi oloro ti won n pe ni kodinni (codeine), ti ko din ni metala.
Christain |
Ohun
ta a gbo ni pe Christian ti won lomo bibi ilu Enugun nipinle Enugun ni lasiri e
tu lakoko to n gbe awon oogun naa lo fun okan lara awon onibaara e ti won ni
won si n wa ona bi won se maa mu.
A gbo pe Christian
lo n ta awon oogun naa fawon eeyan ti won n fa a simu, to si ti so Opolopo awon
to odo awon ti won n muu.
Nigba
ti Christian n b'AWIKONKO soro, o niyalenu lo je foun nigba tawon olopaa da oun
duro pe eru ofin loun ko, toun ko gba ase, sugbon to loun so pe kaadi idanimo
wa lara oun tawon olopaa naa ko si faaye sile lati ye kaadi idanimo naa wo.
"Ko
tii ju osu merin ti mo ti n sise yi. Imo nipa Physiology/Pharmacology ni mo ka
nile eko fasiti ti Nsukka. Odun 2013 ti mo ti se tan ni mi o ti rise se, ti ko
si sibi ti mo fe e gba.
"Mo
n lo lati gbe awon oja naa lo sodo okan lara awon onibara mi to n je Ogbeni Obi
ni, ko to o di pe awon olopaa da mi duro lagbegbe Kara ni Ibafo. Won ko je kin
n soro, ati pe gbogbo bi mo se n gbiyanju lati yo kaadi idanimo mi sita lati fi
ara mi han won ni won ko gba fun mi.
"Ki
tii ju ose meta ti mo mo Ogbeni Obi ni yii, nitori pe o maa n wa ra oja lodo
eni ti mo ti n sise ni. Kii se ayederu oja lawon nkan ti won gba lowo mi yi
nitori onikaluku awon to n ta iru oogun bayii ni won ni awon to n ba won gba a ta
(distributor).
"Nigba
ti won koko mu mi, mi o ro pe o le le to gbogbo eyi to n sele yi nitori pe ere
ni mo koko pe e. Mo ni kaadi idanimo awon ileese yi lowo, gbogbo nkan ni mo se
lati je ki won mo pe emi kii se gbajue tabi okan lara awon janduku."
Agbenuso
fawon olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe iro pata gba a ni Christian n
pa, ati pe oun n wa ona lati we ara e mo ni, eyi ti ko di awon lowo lati foju e
bale ejo lai pe.
Bee lo
ni Ahmed Iliyasu to je Komisana won ti pase pe kawon SARS si maa mu lo sogba
won lati tubo sewadi e daadaa, ki won le tete mo igbese ti won fe e gbe.
No comments:
Post a Comment