Titi di bi e ti n ka iroyin yi loro Tobiloba
Ipense to n fise pasito boju lu awon eeyan ni jibiti si n je fawon araalu,
paapaa awon to n gbe ladugbo Elebute, Ewekoro nitosi Papalanto nipinle Ogun
latari bo se seku pa okan lara awon omo ijo e, Arabinrin Raliatu Ajoke Sanni to
ti bimo mefa losu keta to koja yii.
Ese ko gbero ladugbo Elebute lojo Tusde ose
to koja yi, nigba tawon agbaagba nipinle Ogun bii Komisana olopaa, Olu-Itori,
Olu-Ifo, Oba Owode, awon baale to fi mo Alaaji agba to je egbon Gomina Ibikunle
Amosun loo wo iran pasito naa.
Ko si nnkan to n je koro Tobiloba, eni odun
mejidinlogoji (38) ti won lomo bibi ilu Ilaje nipinle Ondo naa maa se awon
eeyan ni kayeefi bi ko se bi oju e se tutu, to si tun loyaya, iteriba ati irele
sawon eeyan, lai mo pe iranse esu paraku ni.
Tobiloba to je oludasile soosi sele ti won
poruko e ni Holy Gathering Christian Evangelical Church of God la gbo pe o fe e
wonu egbe awo tawon pasito to ba fe e lokiki, to fe maa se awon ayederu ise
iyanu fawon eeyan, ki ero repete si le maa wo ninu soosi won wa.
Won ni lojo kokandinlogun osu keta to koja yi
ni Tobiloba lo sile iyale ile kan ti ko si nile oko mo, eni to je okan lara
awon omo soosi e, Raliatu Ajoke Sanni, eni odun merindinlogoji (36) lati loo ki
ni nnkan bi aago mewa ale, ti won si ni won tun ko ibasun fun ara won lai mo pe
ise buruku to fe e se wa ninu.
Ohun tawon kan n so ni pe oogun ni Tobiloba
fi ba Raliatu sun lale ojo naa, lati ra iye e patapata, nitori ti won so pe se
ni Tobiloba ni ki Raliatu lo ra abela (candle) paali kan pelu agbon lati tan an
yika inu ile, ko si fi agbon si aarin. Won ni nnkan bi aago meta oru ni Raliatu
jade kuro ninu ile lati loo fo agbon naa, sugbon ti ko pada sinu ile naa mo.
AWIKONKO gbo pe Tobiloba koko sebi eni pe oun
ko mo nkankan nipa bi Raliatu se rin in, nitori to so pe osu kokanla odun to
koja lawon ti foju kan ara won gbeyin. Sugbon nigba ti won bere sii te ninu ti
won sib ere sii igbaju bo, se lo sare yi oun pada, to si bere sii ka boroboro
pe oun ko loun pa Raliatu, pasito kan to wa ni Iyana Egbado ti won n pe ni Oba
Majemu lo pa a fun etutu.
Lara awon araadugbo to gbe iroyin kan siwa
leti je ko di mi mo pe iawo Tobiloba maa n sise agbebi, sugbon to je pe opo
igba tawon alaboyun ba bimo sibe, ni won maa n wa ibi omo ti, toro a si di isu
ata yan-an-yan. A gbo pe bale adugbo naa ti ko ri ba soro ti da si oro naa lai
moye igba, ti won si ti kilo fun un pe se ni won maa le e danu kuro ladugbo.
Egbon Raliatu, Dauda Hassan to ni omodun
mejidinlogoji (38) loun so pe ojo kejilelogun ni won n wa aburo oun, ti won si
ranse pe oun bo ya, oun mo nipa bo se rin in, sugbon toun so pe o see se ko lo
ra oja nitori ise aserunloso (hairdresser) lo n se, o si tun n ta oti
elerindodo (Pepsi, Coke, Bottle Water) etc ni Wasinmi.
O loun koko ro pe ere ni, sugbon nigba to di
ojo keta tawon ko ri, lo je koun ati egbon oun loo foro naa to awon olopaa
Itori leti, ti won si bere ise iwadii. Okunrin naa ni okan lara awon omo to n
gbe lodo Raliatu, iyen Damilola Joseph to je omo aburo Raliatu to ti salaisi lo
je kawon tete ri okodoro oro.
Dauda to ni ise fijilante loun n se so pe
gbogbo awon pasito to wa nijoba ibile Ewekoro loun ti loo ba lati beere Raliatu
lowo won, sugbon ti won ni won ko rii, ko too di pe Damilola so fawon, tawon si
loo gbe nile e.
Damilola Joseph ninu oro ti e so pe “Eemeta
ni pasito ti wa sile wa. Lojo ti won maa koko wa si soobu, emi ni mu won lo
sile ti momi wa wa. Lale ojo ti won wa yen ni nnkan bi aago mejo ni, ibi ti mo
ti n yan gaari nitosi ile ni mo wa ki momi too so fun mi pe ti m ba se tan, ki
n wag be ounje mi. Igba ti mo dele ti mi o ri momi, mo wonu ile, mo ri pasito
lori beedi pelu sokoto penpe (boxer) nidii, won n nu ara lowo. Bi mo se n jade
sita, ni mo pade momi ti won n bo lati baluwe, won beere lowo mi pe ki lo de ti
mo fi wonu yara, mo wa a so fun won pe nigba ti mi o ri won. Won ni ki n lo gbe
ounje mi nibi tawon gbe e si.
“Emi o sun ile lojo yen, odo dadi won ni mo
loo sun. Egbon mi to sun sile so pe nigba toun wonu yara, oun ba ti won tan
abela yika, ti momi si jade laago meta oru lati loo fo agbon yen.
Raliatu ti won pa |
Nigba toun naa n soro, Sola to je akobi
oloogbe so pe “SSS1 ni mo wa ni United Comprehensive High School, Wasinmi.
Omodun metadinlogun (17) ni mi. Won jade laarin oru, ko pe ni won tun wole
pada. Nigba to di aago meta oru, won tun jade pada, won ni ki n tilekun leyin.
Igba to di aago mefa, won pada wa a kan ilekun, emi ni mo lo silekun fun won.
Won wa a so fun mi pe ki n toju awon aburo mi daadaa, nitori pe irin ajo tawon
n lo yen ma a pe kawon to o de, ki n ma je ki iya je awon aburo mi.
“Mi mo pasito yen ri, sugbon eekan soso ni
emi ati momi mi lo si soosi won, iyen lojo kerin osu keji ti won se ajodun. Mo
ma n ri won nile wa tele sugbon mi o ri won lojo yen nitori pe mi o si nile. Mo
fe e ki ijoba ran emi ati awon aburo mi lowo, nitori pe ko seni to ma maa toju
wa bi iya wa. Pasito ti jewo ni tesan pe awon ko lawon ge ori, ati pe oun loun
fun won adireesi ile wa, tawon pasito kan fi wa a gbe momi wa.”
Iya Raliatu Arabinrin Olufunmilayo Adebola,
eni odun marundinlogorin (75) ati baba e, Hassan Adebola, eni odun
mejilelaadorun (92) nigba ti won n soro pelu ibanuje okan so pe iku oro ni won
fi pa omo won to fe e je pe oun lo n gbo bukata ebi ju. Bee ni won rawo ebe
sijoba pe ki won ma se je kawon to pawon lekun ale lo lai jiya ese won.
Tobiloba nigba to n soro so pe “Ninu os
kokanla odun to koja ni Arabinrin kan, Oluwakemi Isola mu mi lo sodo Daniel
Sopeju. Latigba baa ni won ti bere sii da mi laamu pe ki n wa wonu egbe awo
won, sugbon mi o gba fun won. Nigba ti won rii pe mi o gba fun won ni won bere
sii dunkoko mo mi pe ti mo ba so pe mi o wonu egbe won, awon maa daran si mi
lorun, ti mi o si ni le gba ara mi sile.
“Won lojokojo tawon omo ijo mi ba lo sori oke
emi, awon a maa pawon leyo kookan. Igba ti wahala naa su mi ni mo beere lowo
Oluwakemi pe wo ni maa se wonu egbe naa, oun lo so fun mi pe ki n ko oruko awon
omo ijo mi wa, awon lawon maa mu oruko eni to ba wu won leyin tawon ba sewadi.
“Mo wa a ko oruko die lara awon omo ijo mi
fun won, ko to o di pe Raliatu ti won n pe ni iya Sola ni won mu. Emi ni mo fun
ni adireesi ati bi won se le rii, iyen lojo Wesde ojo kokanlelogun osu to koja.
Nigba to di nnkan bi aago mewaa ale ojo naa, ni enikan wa kan ilekun ile mi pea
won eeyan n beere mi ninu soosi, mo koko ro pea won ti won wa fun adura ni,
sugbon nigba ti mo jade si won, iyalenu lo je Sopeju ati Oluwakemi ni mo ri
peluu awon marun un ti won aso pupa ati dudu, mi o da awon to ku mo.
Oku Raliatu |
“Mo beere pe ki ni won fe e fi se ati pe bawo
ni won se fe e se eya ara e to ku, won ni lara nkan ti won fi n wo egbe ni. Won
gbe ori yen ati apa e mejeeji sinu ikoko funfun, wi pea won maa jo ni. Igba ti
won ri bi mo se n gbon, ni won ni ki won mu mi lo sinu ile. Igba ti ile mo,
iyawo bi to ri bi mo se n se beere pe ki lo se mi, mo so pe ko si nkankan, mo
wa a lo kaakiri ayika soosi naa lati wo ibi ti won ju oku e si, sugbon mi o
rii.
“Ojo Sande to tele ni mo sakiyesi ninu ofiisi
ti mo n lo ninu soosi naa pe apa pe won wu ile wa nibe, mo wa loo mu (shovel)
lati fi wa ile yen, ki n to o ri pe ibe ni sinku naa si, mo si tun loo bu iyepe
lati tun fi bo o daadaa.
“Iro ni won pa mo mi pe won ri mi nile iya
Sola lale ojo yen, mi o si nibe, looto ni mo ti n lo sile iya Sola, mi o sib a
a dore ikoko. Nkan ti won so fun mi ni pe awon ko le lo eni to ba je eje mi.
Won ti ni ki n jeje pe mi o gbodo so fenikeni, ati pe se ni mo maa ku, idi ni
yii ti mi o fi koko jewo nigba ti won mu mi, nitori mo beru nkan ti won le se
fun mi.
“Ko da a, nigba ti a n bo, Daniel n fesun kan
mi pe ki lo de ki n to jewo, ati pe ti won ba mu mi, se lo ye ki n da je iya mi
ni, wi pe kinni mo fe e ri gba bi won ba pa awa mejeeji.
Daniel ti won tu n pe ni Oba Majemu nigba
toun naa n soro so pe iro ponbele ni Tobiloba pa moun, nitpori pe oun ko mon on
ri, eekan soso loun rii ri. “Omodun mejilelogoji ni mi, omo Abeokuta ni mi.
Kerubu ati Serafu, Oba Majemu niyana Egbado, ni Papalanto si Ewekoro. Mi o si
ninu egbe Kankan, nigba ti mo maa koko mo Tobiloba, omo ijo e kan lo muu wa fun
mi pe ki n gbadura fun un. Igba ti mo maa tun pada ri leekeji, asiko to fe e se
ajodun ninu osu keji odun yi ni, to si fiwe pe mi, mo gbadura fun won, mo si
kuro nibe ni temi.
“Igba to ya ti mo tun maa ri ni mo ri pelu
awon olopaa ti won ni mo wa ninu egbe okunkun kan, gbogbo igba to n so yi, mo
wa lori oke tawon eeyan si wa peluu mi. Emi o mo obinrin yen ri, mi o mo nipa
bi won se pa a. emi ko ni mo jo ori e.
Ohun ta a gbo ni pe yato si pe Tobiloba ti
won so pe ile eko Methodist High School (Private) to wa ni Arigbajo, n ko eko
nipa Isiro, o tun mo nipa eko Oyinbo, Economics, Physics, Chemistry, Biology,
Add Maths, bee la tun gbo pe won tun sese gba a gege bi oluko sile eko giga
Olabisi Onabanjo to wa ni Ago-Iwoye.
Leyin bii wakati meji ti Komisana olopaa
ipinle Ogun Ahmed Iliyasu atawon eeyan to wa lonla gbo pe won sese loo wu oku naa,
ti won si tun ri ikoko ti won tinwon gbe ori atawon owo naa si.
Bee la tun gbo pe awon olopaa tun ri awon
oogun abenugongo nile Oba Majemu ati nile Tobiloba Ipense, ti won si koko wa ba
won logba SARS ti won wa ni Eleweran, iyen ni nnkan bi aago meta aabo osan ojo
Wesde.
Lesekese
tasiri Tobiloba ti tu lawon olopaa ti lo si soosi e lojo Fraide ose to lo lohun
lati daabobo oku naa, ki won ma tun pada wa a wu kuro nibe.
Igba
tawon eeyan paapaa awon odo ilu atawon to wa lati ona jin-jin duro titi de Komisana
olopaa, ti won ko tete rii ni nkan bi aago mejila lawon odo naa bere sii fehonu
han, ti won si bere sii fo ile Tobiloba ati soosi e.
Gbogbo
akitiyan awon olopaa lati dawon eeyan lowo ko lo ja si pabo, ko da toro naa tun
fe e dija igboro laarin olopaa atawon odo naa, to je pe die lo ku ki won fokuta
fo oga olopaa, iyen Area Commander Ota lori, sugbon ti Olorun ko o yo.
Awon
odo adugbo naa la gbo pe won dana sun ile Tobiloba Ipense pelu ile kan to wa
legbe e, ti won ni okan lara awon omo ijo lo nii. Bee la tun gbo pe awon SARS
lo be awon odo naa lati ma dana sun ile iya iyawo Tobiloba to wa legbe e.
Titi
di bi e ti n ka iroyin yi la gbo pe Oba Majemu ko tii jewo, sugbon ta a gbo pe
oga olopaa SARS, iyen OC SARS dunkoko mo on pe bi ko ba ti jewo, awon yoo wa
gbogbo ebi e kan lati lawon run, ayafi to ba jewo.
No comments:
Post a Comment