Won Ni Ise Sorosoro Ko Pe Awolowo Mo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 8, 2018

Won Ni Ise Sorosoro Ko Pe Awolowo Mo

Bi iroyin to n lo kaakiri igboro nipa boi boya maanu gbajumo sorosoro ori redio ati telifisan nni, Olumide Awolowo tawon eeyan tun n pe ni Orobo Presenter ba fi le je otito, a je pe won ti pada geeti e gidi gan an ni, tabi ko je pe okunrin naa ko tii mo ona to fe e gba mo.

Olumide Awolowo to maa n figboya soro wi pe oun gba pe oun lagidi, to si je pe lori awijare ati otito loun maa n sagidi le lori la gbo pe o ti fise sorosoro to fi di gbajumo naa sile, to si je pe ise kan ti ko tii fibe ye awon eeyan daadaa lo rawo le bayii.

Okunrin naa ti won tun n pe ni Gedu Master lo pa gbogbo awon eto e lori redio ati telifisan lo ti pati lati nkan bi odun meji seyin, to je pe ise sogun-dogoji lo n se, to si n so pe kawon eeyan wa di olowo yanturu.

AWIKONKO gbo pe ileese redio Sweet pelu atileyin awon omo egbe sorosoro fun Awolowo ni anfaani lati maa seto laago meje koja iseju meedogun (7:15pm) ni gbogbo irole ojo Wesde lati maa fi seto, sugbon to je pe kaka ko se eto tawon eeyan n fe e gbo lati odo e, oro wi pe kawon eeyan wa a di olowo-oloro lo n so.

A ti e tun gbo pe eto kan wa to n se lori redio Family to wa niluu Abeokuta, eyi to pe ni 'S'Alaafia Ni' to tun n dogbon lo anfaani e lati fi polowo oja e naa.

Olumide Awolowo to je pe nise lawon eeyan maa n pe gege bi MC sawon ode ariya tele sere paapaa nigba toun ati Oloye Sunday Ogunsola, iyen Tantala si jo maa n kaakiri, lo ti wa a di eni tise naa ko too jeun mo.

Lara awon to sunmo Awolowo to je ka mo bo se n lo so pe okunrin naa maa n so pe ise to sese gba naa te e lorun ju ise sorosoro, toun ko si le fi sere. Eni naa ta a foruko bo lasiri so pe opo anfaani toun ti je lori ise naa ti ju ti sorosoro lo.

Nkan to ti e tun n se awon eeyan ni kayeefi ni bi ko se seni to mo esin tokunrin naa n sin, nitori pe bi e ba se n rii ni soosi, le maa ri ni mosalasi, bee naa le maa tun ba a pade lodo awon onisese.

Kii se asodun wi pe Awolowo gan an maa n pe ara e ni Ajihinrere, Afaa ati Awise, bo tile je pe a ko tii gbo nipa ilu to ti je Awise, ati eni to fun un loye naa.

Sa o, kii se asodun tabi aheso wi pe opo awon to gba oro ati ise ti agba sorosoro naa n so ni won ti je anfaani repete, ko da a, ti won si tun n je anfaani naa lowolowo titi di bi e ti n karoyin yi.

Egberun kan ati igba (#1200) naira la gbo pe awon to n ro lo si ofiisi Awolowo to wa ni Iyana Mosuari lati darapo ni won ti n di olowo repete, ti won si tun un gba awon ebun bii foonu, ayoonu (pressing iron), jenereto, moto atawon ebun min in tileese FSOWER sagbateru e.

Bee la tun gbo pe nipele-nipele ni eto to n so awon eeyan d'oloro naa wa, to si je pe anfaani wa fawon to ba n se e wi pe awon ko se mo. Awon anfaani tokunrin naa n je ninu ise yi lo da bi eni pe o fa a to fi so pe koun kuku fara si daadaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI