Pelu bi nkan se n lo yi, afaimo kawon ti won ko fe ki Seneto to n soju ekun Lagos West nile igbimo asofin agba niluu Abuja, Seneto Solomon Olamilekan Adeola tawon eeyan tun n pe ni Yayi di gomina nipinle Ogun ma ba ti e je patapata lodo ajo INEC pelu bi won se lawon kan loo le awon alemode, iyen posita (poster) ipolongo idibo e kaakiri ipinle naa bayii.
Ohun ta a gbo ni pe oru ojo Tosde mojumo Fraide to koja yi la gbo pe awon kan loo le awon posita kaakiri awon agbegbe bii Sango, Ifo ati Abeokuta leyi to tako ofin ati ilana ajo eleto idibo, iyen INEC, to si see se ki ajo naa fofin de e lati dije ninu eto idibo odun 2019 to m bo lona.
AWIKONKO gbo pe awon to sunmo Seneto Yayi toun naa n gbaradi lati jade dupo gomina, to si ti n se orisirisi ipade pelu awon agbaagba nidi oselu nipinle Ogun fun ifowosowopo won ni won ta a lolobo pe awon ti n ri awon posita e kaakiri igboro ipinle Ogun.
A gbo pe okunrin danku naa koko ka oro naa si awada, sugbon nigba ti won fi awon aworan awon aposita naa ranse si lori foonu e, la gbo pe o fe e le maa to sara nibi to wa, pelu bo se mo ohun ti yoo teyin iru nkan be e yo.
Lesekese lo ti sare gbe atejade sita fawon oniroyin pe oun ko mo nkankan nipa awon alemode naa, ati pe o see se ko je pe awon alatako ti ko fe koun de ipo toun ti n la ala e lati nkan bi odun merin seyin ni won wa nidi e.
Ninu atejade naa ni Yayi so pe "Gege bi eni to n tele ofin, to si tun je asofin fun odun merinla, to si tun je okan lara awon asofin agba lorileede Naijiria, emi ko ye lenu ti won yoo maa ri gege bi arufin latari pe bo ya mo fe e du ipo kan.
" Gege bi ofin eleto idibo lorileede Naijiria, o je nkan ti ko tona fun eyikeyi adije sipo lodun 2019 lati bere ipolongo oselu gege bi won se ko o sinu awon alemode ti won le Foto mi mo, eyi ti won n le.kaakiri ipinle Ogun."
Okunrin naa loun mo awon to n binu latari awon irin ati ipade abele lorisirisi toun n se pelu awon agbaagba nidi oselu, toun ki si nii gbero buburu, eyi ti yoo je ki won fofin de oun lati kopa ninu eto idi odun 2019.
No comments:
Post a Comment