Bi
iroyin to n lo kaakiri igboro nipa egbe apapo olorin nipinle Ogun, iyen egbe
Performing Musicians Association of Nigeria (PMAN) ba fi le je otito oro, a je
pe a fi kawon omo egbe naa tete fimo sokan lati gba alaafia ati isokan laaye
ninu egbe lati dekun wahala ojo iwaju.
SAMMY B |
Gege
bi iroyin to te AWIKONKO lowo lose to koja se so, a gbo pe ojo Wesde ose to m
bo yi, iyen ojo keje osu keta la gbo pe o ye ki won se ibura fawon oloye tuntun
ti won idibo yan, sugbon ti won ti ye ojo naa.
A gbo
pe o seese ki won fofin de awon oloye to ye ki won bura fun yi, ti Sam Owo je
olori won, ti ko si ni seni to maa gburo won mo lai lai pelu bi won se so pe
awuruju ni won fi yan ara won sipo.
Ohun
ti a gbo ni pe won ti yan awon oloye kan lati sagbekale eto idibo miran, eyi ti
won so pe gbajumo olorin nni, Sammy B ni olori igbimo naa.
AWIKONKO
gbo pe Sammy B to je ojulowo akowe egbe tawon oloye egbe lapapo fun niwe ase ko
gbo nipa bi won se seto idibo naa, ti won si fe e fona eburu yo o nipo.
Bo
tile je pe laarin bii odun mejo seyin ni won so pe egbe Pman ti ku nipinle Ogun
sugbon ta a gbo pe opelope Sam Owo ti won lo tun da pada to si ko awon eeyan jo
lati jii dide.
Nibi
ti ipade alaafia ti akowe egbe lapapo dari e ti n loo lowo ni wahala ti be sile
laarin igun mejeeji ti won si bere si fee maa yowo ese si ara won, o si ku die
ki won ju ara won sinu omi legbe ibi ti ipade naa ti waye ni ooteli Ceaser to
wa ni Ibara niluu Abeokuta.
Fun
bii wakati kan gbako ki won too yanju oro naa, eyi lo sii fa ti Taju System
atawon olori egbe lapapo se fa ibinu yo pe ̣peluu bi won se n se yii, won yoo
fofin de egbe naa nipinle Ogun.
AWIKONKO
gbo pe leyinoreyin lawon oloye egbe PMAN lapapo wa da agbara egbe pada sodo
Sammy B ti won si ni ko mu Sam Owo mora lati seto ibo min in laarin egbe naa.
Loju
ese si ni won ti ni ki SAMMY B je alaga igbimo to maa seto ibo, awon yooku ti
won yoo sise pẹ̀lúu e ni Sego Alaafia, Ogbeni Animasahun, ati Ọ̀gbẹ́ni Oladele
Eleganzar.
Peluu
gbogbo e naa, wahala si wa nitori awon onifuji ti so pe awon nipo alaga
egbe naa to si gege bi awon se maa n to.
No comments:
Post a Comment