Oselu Bere: Won Ni Won Yeye Paseda Nita Gbangba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, March 31, 2018

Oselu Bere: Won Ni Won Yeye Paseda Nita Gbangba

Titi di bi e ti n ka iroyin yi, ko tii seni to le so abajade ti yoo teyin bi won se yeye oludije sipo gomina nipinle Ogun lodun 2015, Omoba Olatunde Olarotimi Paseda, eni to tun n gbero lati jade dupo naa lodun 2019 nibi ipade kan to waye lai pe yii.

Ojo manigbagbe lojo Tosde to koja yi je fun Otunba Rotimi Paseda to je agba onisowo nni, to tun je asiwaju egbe oselu UPN lorileede Naijiria, ti ko si le gbagbe lailai pelu bi won se fi oselu han an.

Gege b'AWIKONKO se gbo, awon omo egbe oselu Unity Party of Nigeria ti won fe e jade dupo lodun 2019 ni won gbe eto kan kale ninu ogba ile egbe naa to wa ni adugbo Onikolobo niluu Abeokuta lati fi fa oju awon araalu mora.

A gbo pe se lawon omo egbe naa loo fi owo ya awon eeyan lati wa a bu ola fun oga won, ki won si le fi gba owo lowo e bi won ba pari.

Awon toro naa soju won so pe bo tile je pe Paseda ko mo nkankan nipa eto naa tele, sugbon ti won ranse pe e pe ko wa bawon eeyan soro, kawon ti yoo tele e lakoko ti ipolongo idibo ba bere ni pereu, toun naa si gba lati wa.

Bo tile je pe ohun ta a gbo ni pe awon eeyan naa ko mo pe Paseda yoo wa sibi eto naa lojo naa, ti won ro pe kawon se e, kawon si fi foto ranse sii, ko le fi owo ranse si won, sugbon ti okunrin naa yo si won bi ojo.

Iyalenu lo je pe nigba ti Paseda de be, se lawon eeyan ti won ti won ba duna-dura pe won yoo san owo fun leyin eto naa bere sii pariwo oruko Paseda, ti inu oun naa si n dun lai mo pe Eerin (Elephant) ti won fe e ye aga mo nidi loun.

Orin 'A o mu Eerin joba' tawon eeyan naa n ko ni Paseda si n fese rajo si, ki oro to o yi pada, ti won yi ohun pada.

A gbo se lawon ti won n korin yin Paseda bere sii pariwo oruko olori ile igbimo asofin ipinle Ogun, ti won n so pe 'Ishola Adekunbi la fe, a o fe Paseda', 'Paseda gbe Adekunbi jade'. 

Awon to gbe oro naa si wa leti so pe o gba awon to sagbekale eto naa ni iseju mewaa lati pa won lenu mo, to si je pe se ni Paseda binu kuro nibe lojo naa lai gbe owo kale fun won gege bi won se n reti owo latodo e.

Won ni gbogbo ero okan Paseda ni pe awon eeyan naa ti gbabodi, ti won si fe e mon on mo yeye oun nita gbangba ni. Bee la tun gbo pe egbe oselu UPN ti Paseda n se naa tun ti n fe e daru patapata bayii.

Iroyin to te AWIKONKO lowo je ko ye wa pe Paseda funra e ti bere sii yo ese awon omo egbe e lawo nikookan, nitori ta a gbo pe awon yen naa ti n ledi apo po pelu awon oloselu min in.

Ohun to n ya awon eeyan lenu ni bo tun se je inu ile egbe naa to je pe Paseda lo n san owo e ni won ti yeye e, ti oju si tii kuro nibe, sugbon toun naa se bi okunrin.

Agbenuso fun Otunba Paseda, Ogbeni Michael Ogunsiji nigba to n tako oro naa so pe iro nla to jinna si otito ni oro naa, ati pe awon kan to n sise fun Paseda tele, sugbon ti won le danu nitori ti won gbabodi ni won wa nidi iroyin eleje naa lati ba oruko Paseda je.

O ni opo otelemuye lo wa nibi eto naa lojo naa, lati ma je ki wahala sele, ko da a to tun so pe opo awon oniroyin lo wa nibe lojo naa, ti ko si seni to ko iru iroyin bee jade sita.

Michael tun so pe, awon omo egbe ti won fe e dupo omo ile igbimo asofin ni won gbe eto naa kale, to si je pe awon ti won wa nibe lojo naa, awon omo egbe UPN ni gbogbo, ti ko si seni ti kii se omo egbe ni be.

Okunrin naa ni to ba je pe looto ni iroyin naa, ki.lo fa a ti won ko fi awon foto ati fidio isele naa sita fawon eeyan lati ri, ki won si le gbagbo pe looto ni nnkan bee waye.

O wa ro awon to n gbe iroyin naa kaakiri ori ero ayelujara lati dekun nnkan bee, bi bee ko, won yoo kan idin ninu iyo. Bakan naa lo gbawon araalu lamoran pe ki won ma se gba iroyin naa gbo nitori pe oselu lawon to fe e ba oruko Paseda je fe e fi se, lati fi tako o lakoko eto idibo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI