Ori Ko Sanni Yo Lowo Awon Ajinigbe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 1, 2018

Ori Ko Sanni Yo Lowo Awon Ajinigbe

Bi kii ba a se ori to ko gendekunrin kan ti won poruko e ni Sanni Dan Nasarawa yo lowo awon ajinigbe lojo Tosde ojo kinni, osu keji to koja yi ni, bo ya won ki ba ti gbemi e nigba ti won ko tete ri eeyan lati wa gba a sile pelu owo ti won beere lowo awon eeyan e.

Iroyin to te AWIKONKO lowo je ko ye wa pe ose to lo lohun lawon ajinigbe naa jii gbe niluu Ilaro, ti won sig be e lo sinu igbo aginju nla kan, nibi ti won loo de e mole si.

Sugbon nise ni okete ri aaye bo iru nigba ti okun ti won fi so o mole dee de tu, to si tete ba ese e soro lasiko ti won lawon to jii gbe ti sun lo fonfon.

AWIKONKO gbo pe bi Sanni se igboro lo ti gba ileese olopaa FSARS to wa ni Magbon niluu Abeokuta lo lati lo fi to won leti, tawon yen si gbera lati tele lo ni nnkan bi aago mefa irole ojo Tosde naa.

Fun bii wakati mewaa gbako la gbo pe Sanni fi mu awon SARS yipo inu igbo naa lati wa won ri, sugbon ti asiri won pada tu ni nnkan bii aago merin afejumomo ojo Fraide to koja yin a.

A fi bi eni pea won ajinigbe naa ti n reti awon olopaa SARS tele lori, nitori bi won se kofiri won layika ti won sapamo si ni won ti ki ibon won mole, ti won sib ere sii yin fun won, sugbon tawon SARS naa ko da a pada fun won.

Leyin-o-reyin la gbo pe ibon ba okan lara won, tiyen ku lesekese, nigba tawon meje to kun a papa bora nigba ti won rii pe agbara won ko ka awon olopaa SARS naa mo.

Sanni nigba to n soro so pe iya ni won fi n je oun lojoojumo, ti won tun da ogbe soun lara nitori ti won ko ri eeyan yoju latyi wa fowo gba oun sile, bee lo so pe eekan lojumo loun n jeun lahamo won.

Ahmed Iliyasu nigba to n jeri soro naa so pe looto ni, ati pe yato si eni ti won pa ninu won, awon bii meje lo salo pelu ota ibon lara. O ni awon gba ibon AK47 to gba ota ibon meedogun leekan soso lowo eni to dagbere faye lasiko ikolu naa.

Iliyasu wa ro awon araalu papa awon ile iwosan wi pe ki won tete fi to awon olopaa leti, bi won ba kofiri enikeni to ba ni ogbe ota ibon lara, ki ise olopaa le tubo kesejare. Bee lo ni ki won tubo maa nigbagbo ninu awon olopaa fun eto aabo to peye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI