Kani
odomokunrin eni odun marundinlogbon (25), Babalola Alex ati ore e ti won
n pe ni Ijebu toun tin a papa bora mo pe omi yoo pada wogbin won lenu latari
oogun owo ti won fe e se ni, boy a won ki ba ti duro de asiko Olorun fun ayanmo
won.
Ni nkan
bi aago mejila osan ojo Tosde ose to koja la gbo pe asiri Alex ati ore e tu
sita lagbegbe Asese nipinle Ogun lasiko ti won loo hu ori oku ti won ti sin
tipe nite oku kan lagbegbe naa.
Okan
lara awon to n gbe lagbegbe naa la gbo pe o ta awon olopaa SARS lolobo lasiko
tawon yen n sise koja. Okunrin naa la gbo pe o so fawon SARS naa wi pe asiko
toun loo yagbe ninu igbon loun ri awon ore meji naa ti won n ki nkan to jo ori
oku bo inu baagi ti won gbe dani.
Lesekese
tawon olopaa naa ti gbo ni won ti sare lo sibe lati look o won, sugbon nigba ti
won maa de be, Alex nikan ni won ri pelu baagi owo to gbe dani.
Bo tile
je pe se ni Alex koko paro fawon olopaa naa nigba ti won n beere lowo e pe ki
lo wa ninu baagi to gbe dani pe aso toun fe e lo fo lo wa ninu e, sugbon nigba
ti won maa tuu, iyalenu lo je pe ori oku lo wa ninu e.
Basiri
e se tu sita lo ti bere sii bebe wi pe ki won se oun jeje, ati pea won meji ni,
tenikan to ku ti salo nigba to kefiri pea won SARS ti n bo. Alex so pe odo
babalawo toun ati ore oun to n je Ijebu lo lati lo dogbon soro ara won, nipa si
se oogun owo lo ni kawon loo wa ori oku wa, idi ni yii tawon fi loo hu ori oku
naa.
Awon
SARS naa la gbo pe won tun ko won lo sodo Baale Asese, Oloye Kasumu Sonola to
bu enu ate lu iwa tawon eeyan naa hu, bee lo rawo ebe sawon olopaa na wi pe ki
won tubo bawon sise lati ri awon odaran naa mu.
Bi
iroyin naa ti kan Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu leti lo ti pase pe kawon SARS
tesiwaju ninu ise iwadii won, ki won si tubo foro wa Alex lenu wo lati ri Ijebu
to salo mu, kawon le tete bere igbese lati foju won bale ejo.
No comments:
Post a Comment