O Ma Se O: Gbajumo Sorosoro Padanu Baba E - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, March 10, 2018

O Ma Se O: Gbajumo Sorosoro Padanu Baba E

Titi di bi e ti n ka iroyin yi ni okan lara awon oga agba nidi ise sorosoro niluu Abeokuta, ipinle Ogun, Babatunde Okunade tawon eeyan n pe ni Omoba si fi wa ninu ironu ti baba e, Omoba Vincent Adefolu Okunade to ku lojo kinni in osu yii.
Oloogbe naa
Bo tile je pe kii se baba naa lo bii, sugbon to je pe baba naa lo to o lati kekere titi digba to fi dagba, ta a si tun gbo pe Oloogbe naa lo fi senu ise sorosoro lodo Oloogbe Atobatele Opaleye Iyeru Okin tawon ololufe e mo si Baba Opii.
Gege b’AWIKONKO se gbo, oloogbe naa, Omoba Vincent Adefolu Okunade ni won fi j’oba ilu Isaga Orile lodun 1982 lati idile Odusina Oluyobu, to si je pe oun gan an ni Oba Oge II, sugbon ti won pada ro o loye ni kootu lodun 1987 leyin odun marun to dori ipere awon baba nla e.
Titi digba to fi papoda la gbo pe awon omo bibi ilu Isaga Orile atawon to mon on daadaa si fi n pe ni Kabiyesi, nitori ta a gbo pe oun gan an ni won jawe oye le lori, to si tun se osu meta gbako n’Ipebi ile ogboni ti ilu Isaga Orile.
AWIKONKO gbo pe aisan ojo ogbo lo se Oloogbe Omoba Okunade  ko too di pe elemin in gba a leni odun marundinlaadorun (85) lojo kinni in osu ta a wa yii, ta a ti e tun gbo pe ara baba naa ti n ya.
Omoba Babatunde Okunade
Bee la tun gbo pe awon molebi oloogbe naa ti mu ojo ti won yoo te baba na si afefe rere, ti won yoo si sayeye ikeyin fun un, iyen ninu osu kerin to n bo.
Isin onigbagbo la gbo pe yoo waye lojo kejila osu kerin ninu ijo St Andrew Anglican to wa ni Ibara, Omida, Abeokuta, ti won yoo si tun seto eye ikeyin nile baba naa to wa ni Road B, Block 5, Isokan Estate, Muraina, Ayetoro Road, Abeokuta.
Ayeye weje-wemu fawon alejo la gbo pe yoo waye nileewe alakobere St Annes to wa ni Oke-Ilewo, Abeokuta. Fun alaye lekunrere, e le pe Omoba Babatunde Okunade sori foonu e, 08032370756.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI