Asiri Daniel Ogbologbo Adigunjale to n fise Pasito Boju tu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 1, 2018

Asiri Daniel Ogbologbo Adigunjale to n fise Pasito Boju tu

Opo awon to mo Daniel Onwugbufor gege bi iranse Olorun, to tun je Oludasile soosi God's Favour Ministry to wa lagbegbe Iba niluu Eko loro naa si n ya lenu titi di bi e ti n ka iroyin yi, pelu basiri e se tu sawon olopaa lowo wi pe okan lara awon ogbologbo adigunjale ni, to tun maa n bawon adigunjale ta moto ti won ba ji gbo tan leyin toun naa ba ti lo fungba die.

Ojo Tosde, ojo kinni osu to koja yi lasiri Daniel tu sita nigba tawon olopaa sewadi moto jiipu Lexus RX 330 kan de ile e, eyi ti won so pe awon adigunjale gba lowo eni to nii, to si ti ta moto naa si Onitsha.

Bo tile je pe se ni won so pe Daniel oun ko mo nkankan nipa moto ti won so, sugbon nigba ti won fawon eri aridaju kan han an, lo too jewo fun won pe ki won se oun jeje nitori pe ise esu ni.

Nigba tasiri tu lo je ki won mo pe odomokunrin kan tojo ori e ko tii ju odun mejidinlogbon (28) lo, iyen Israel Animasaun lo gbe moto naa foun pe koun ba won ta, to si tun so pe oun ko mo pe ise adigunjale lo n se.

AWIKONKO gbo pe nigba towo te Israel loun naa jewo pe Daniel lo maa n ba won ta gbogbo moto tawon ba ti ji gbe siluu Onitsha nibi tasiri ko ti ni tu sita.

Israel so pe awon meta lawon fibon gba moto naa lagbegbe Ajah niluu Eko, toun si gbe e lo fun Daniel to maa n bawon ta moto tawon ba ja gba, bee lo so pe  350,000 loun si gba ninu owo moto naa lowo Daniel leyin to lo fun ose meji.

Israel tun so siwaju pe lai pe loun jale foonu olowo nla kan, Samsung Galaxy, to je pe egberun marundinlogoji (35,000) naira pere ni Daniel foun fun foonu naa.

Daniel wa bebe pe bi won ba foju aanu wo oun, ti won si foun laaye, bo tile je pe oun ti gbe moto naa fenikan ni Onitsha, oun yoo ran awon olopaa lowo lori ona ti won le gba lati gba moto naa pada lowo eni toun gbe e fun.

Titi digba ti a sokojopo iroyin yi tan la gbo pe iwadii si n lo lowo lati gba moto naa pada, bee ni Ahmed Iliyasu to je Komisana olopaa tun ti pase pe kawon SARS rii daju pe owo te awon meji to ku ti won jo ja moto naa gba lati le tete foju won bale ejo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI