Ipo Baale Da Wahala Sile Ni Waterside - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 1, 2018

Ipo Baale Da Wahala Sile Ni Waterside

Bo tile je pe Onarebu Adeyemi Harrison to n soju agbegbe Waterside nile igbimo asofin ipinle Ogun ti so pe igbese ti n lo lati yanju wahala nla kan to be sile lojo Sande ose to koja yi, sugbon titi digba ta a sakojopo iroyin yi tan ni nkan ko tii fi be e rogbo niluu Ayila ti wahala ti n sele, nibi ti won ti seku pa Bayo Oluseyi, ti won si tun fo igi mo odomokunrin kan ti a ko tii moruko titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan lori lojo Fraide ose to lo lohun.

Iroyin to te AWIKONKO lowo je ko ye wa pe ipo Baale lo da wahala sile toro si di boolo o yago, ti olomo ko mo omo e mo, ti wahala naa si fe e da bi oogun abele ti Adubi, tawon araalu Ayila si n ko eru won kuro niluu lo si awon ilu to sunmo won bii Ilu Tuntun lati lo maa gbe.

Ohun ta a gbo ni pe Ogbeni Abajo Musa to je alaga ijoba ibile idagbasoke Ogun Waterside East la gbo pe o je gege bii igi leyin ogba fun wahala naa, nitori bi won loo se fa enikan, Ogbeni Akinbote, eni ti won lawon araalu ko gba tie kale gege bii Baale, to si so pe dandan eni toun fe ni yen.

A gbo pe odun 1957 ni wahala lori ipo Baale naa ti bere sugbon ti won pada yanju e, eyi ti won si pin ipo naa fun idile marun, awon idile na ni idile Akarigbo, Gbikenhun, Oliropo, Olowosanyeje ati Orukotan.

AWIKONKO gbo pe nigba ti won bere pinpin ipo naa, idile Orukotan lo n wa lori ipo naa, ti won si gba pe idile naa ni yoo gbeyin, tonikaluku won si n gbe igbesi aye alaafia.

Ohun ta a tun gbo ni pe leyin ti Baale lati idile Orukotan papoda, tasiko to fun idile Akarigbo lati je, ni won so pe ko tii seni tawon yoo fa kale lati je Baale, ki won lo si idile Gbikenhun, sugbon tawon yen naa so pe awon ko tii setan nitori ti ko tii seni tawon yoo fa kale.

Awon bii Oloye H.I. Akarigbo, Oloye I.O Menegan, Oloye J. Ehinmosan, Oloye Ogunjumakin Lagunogho ati Ogbeni Lawrence Adegbohu lati idile Akarigbo fowo siwe pea won ko tii setan lati di Baale.

Eyi lo fa a ti won fi yan Oloogbe Oloye Akinlonu lati idile Oliropo kale gege bi Baale, eni ta a gbo pe aimoye odun lo fi je, sugbon toun naa pada ku lai pe yii.

Lara awon to gbe isele naa si wa leti je ko ye w ape idile Olowosanyeje nipo naa kan, gege bi won se laa kale lodun 1957, tawon naa si Oloye Akinbote kale, sugbon ti won so pe se lawon idile Akarigbo fariga wi pea won ti setan lati gba ipo naa nitori tawon ti ri eni tawon yoo fa kale.

Eyi gan an la gbo pe o da wahala nla naa sile, nitori bawon idile meta toku se fowo sii pe idile Olowosanyeje nipo naa kan, kii se Akarigbo.

Okan lara awon omo ilu naa to ni ka foruko boun lasiri so pe bo tile je pe oun ko fe e soro nitori oro naa ti n di toro oselu, tie sin toun si n sin gege bi onigbagbo ko faaye gba eleyameya, sugbon toun ko ni sai so ododo pe alaafia ilu ni Onarebu Musa Abajo ti won fesun kan n wa, kii se oun lo yan Baale fun won ati pe ija ti won n ja ko lese nile.

Lati fidi isele naa mule akoroyin wa gbiyanju lati fi atejise ranse si Oloye Babajide Ojuko to je Komisana foro ijoba ibile ati oye jije nipinle Ogun, ti ko sit ii da esi atejise wa pada titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan.

Bakan naa la tun gbiyanju lati ba Ogbeni Abimbola Oyeyemi to je agbenuso fawon olopaa soro lori wahala to n sele naa soro, sugbon ti ko tii da esi pada fun wa titi dasiko yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI