Olusadile ajo alaanu nni, Paseda Legacy Foundation, Omoba Rotimi Paseda ti so pe opo awon oloselu lorileede Naijiria lo maa na awon owo anadanu lori idibo odun 2019 to m bo lona, nitori pe oju awon araalu ti la, iye won si ti si.
Paseda to je adije sipo gomina ipinle Ogun lodun 2015 labe egbe oselu UPN soro yi nile egbe naa to wa ladugbo Onikolobo niluu Abeokuta lojo Tosde to koja yi lakoko to n fa owo awon omo egbe meta to fe e jade dupo omo ile igbimo asofin ipinle naa.
O ni oju yoo ti opo awon oloselu ti agbekele owo ti won fe e na, tabi wi pe awon yoo ji apoti idibo gbe lojo idibo, nitori pe ko nii si aaye fun si se awuruju lojo naa, bi ko se pe awon oludije tawon araalu ba mo pe o kun oju osuwon, to si ni opolopo anfaani ti won le jere lara e ni yoo wole.
Gbajumo oloselu to tun gba esin gbo gidigidi naa so pe awon araalu yoo dibo fun eni ti okan won ba fe lodun 2019 lati gba ara won sile ninu iponju ati airije ti won n koju lojoojumo.
Ninu oro e, o so pe "Asiko to le lawon araalu n koju, iponju naa po debi pe won n wa ayipada rere bii temi. Mo fe e fi da a yin loju pe oju yoo ti owo ati yiyi esi ibo nitori pe se lawon eeyan yoo dibo fun eni ti okan won n fe.
"Ni nkan bi osu meta digba ta a wa yi, e maa ri bawon eeyan se ma maa ro wa sibi. Kii se pe a maa gbe owo fun won gege ba a se se lakoko idibo to koja, nitori pe a ti jeere okan won. Won n fe ayipada too to, kii se iro ati etanje.
"Opo awon omo ile igbimo asofin ta a ni lonii lo je pe ase oga won ni won n tele e. Emi o nii yan omo ile igbimo kankan. A maa gba won lamoran lati dide pe mi nija, ki n le se daadaa, ti won a si lanfaani lati beere ibeere to ba n gbe won lokan, paapaa lori bi a se n na owo."
Nigba to n soro lori isoro to n fa orileede Naijiria seyin, Otunba Paseda so pe nkan meta pere lo n dabaru orileede yii, awon naa ni 'esin', 'eleyameya' ati 'si se akanse ise si ekun ti adari ba ti jade' lai se sawon agbegbe to ku to wa labe iru adari be e, tawon si gbodo paarun ninu oselu.
Ninu or ti e, Alaga egbe oselu UPN nipinle Ogun, Alaaja Aminat Olatunbosun gba awon omo egbe naa lamoran pe ki won tubo fi kun un okun ati agbara won, nitori pe egbe oselu won nikan lawon araalu tun n wo gege bi ireti won.
O ni "Egbe oselu PDP ti wa, won ti ja awon araalu kule. APC lo wa nijoba bayii, tawon naa si ti padanu igbagbo tawon eeyan ni si won. Ni bayii, egbe UPN wa ni won tun n wo bayii lati koju awon isoro ta a ni. Awa naa ti n gbiyanju lati ba won soro pe awa ko nii ja won kule gege bawon egbe oselu to ku ti se.
No comments:
Post a Comment