Lati le dawo iwa odaran
duro kaakiri orileede yi, paapaa nipinle Ogun, ajo ojulalakanfinsori, iyen
fijilante ijoba apapo (Vigilante Group of Nigeria), VGN eka tipinle Ogun ti
bere idanilekoo olojo merin fawon osise e kaakiri.
Idanilekoo naa to bere
lonii ojo Fraide, ojo kerindinlogun osu keta odun 2018 lo bere pelu iforuko awon
akopa sile ninu ogba ileese naa to wa ladugbo Kuforiji Olubi, Adigbe, Abeokuta.
Gege bi Oludari egbe
Fijilante (VGN) nipinle Ogun, Ogbeni Olanrewaju Nureni Adedoyin se so, o so pe
idanilekoo naa wa lati je kawon osise won mo awon ona tuntun tawon onise ibi n
gba sise buruku won lawon awujo orileede Naijiria, ati lati wa ni imurasile fun
bi won se n reti esi lati odo Aare orileede yi, Ogagun Muhammadu Buhari lati so
egbe naa di ofin.
Adedoyin so pe ko to o di
pe Aare Buhari bu owo lu iwe won to ti wa lori tabili e, leyin tawon omo ile
igbimo asofin mejeeji ti bu owo luu, dandan ni kawon wa ni imurasile lati mo
ise ti won gba, ki eto aabo to pe ye le wa laarin ilu.
O je ko di mi mo pe kii se
pe egbe naa lo mon on mo gbe idanilekoo olojo merin naa kale, bi ko se pe
igbimo to n ri soro olopaa nile igbimo asofin niluu Abuja, iyen Committee of
Police Affairs pelu ajosepo ileese kan to pe ni Institute of Corporate Security
and Intelligence Limited lo gbe eto naa kale nibi tawon agbaagba leka eto aabo
yoo ti wa a dawon omo egbe won lekoo.
Olanrewaju tun so pe kii
se idanilekoo akoko tawon yoo se ni yii, sugbon ona ti idanilekoo yi gba waye yoo
yato si eyi tawon ti n se tele, latari awon to gbe e kale, ti kii se pe egbe
won lo deedee ronu nipa e, nitori pe lore-koore lawon maa n se e.
Bee lo fokan awon araalu
bale pe ki won ma reti abajade to se e fokan tan leyin tawon ba pari idanilekoo
na, nitori pe emi ati dukia awon araalu lo je VGN logun, ti won si gbodo mu eto
aabo lokunkundun.
Bakan naa lo gba awon omo egbe
naa lamoran pe ki won rii daju pe won foju, feti si gbogbo nkan ti won ba ko
won nibi idanilekoo naa, ki won si muu lo. O tun je ki won mo pe ko seni to
koja ofin, nitori naa, ki won ma se ri aso egbe naa gege bii pe ko seni to le
mu won bi won ba wo o.
No comments:
Post a Comment