Bi e ba n so nipa awon to kosemose nidi ka dari sinima, ka ko pa ninu sinima, odu ni Oluwadamilare Agbejo tawon eeyan mo si Filefun to je omo bibi ipinle Ekiti sugbon to filuu Abeokuta sebugbe. Damilare ti won tun n pe ni Konfaamu so pe ninu awon marun un tawon jo bere ise tiata lodun 1997, oun ati Odunlade Adekola lawon seku. O lawon meji ti ku, tenikan si ti fise naa sile. O soro naa lakoko to n b'AWIKONKO soro lai pe yii. E ka bi iforowero naa se loo si.
AWIKONKO: Oruko yin lekunrere?
FILEFUN: Oruko mi ni Oluwadamilare Agbejo tawon eeyan mo si KONFAAMU, bee ni won tun n pe mi ni FIlefun.
AWIKONKO: Bawo le se bere ise tiata?
FILEFUN: Eeyan kan wa ti mi o ki n gbagbe, nitori pe awon oga kan wa to je pe ko sibi ti de, ti e ba ti gbo oruko won, e maa mo pe eeyan le tele, eni naa ni Kayode Akindina. Nigba ti a de, won tewo gba wa pelu ife. Emi pelu awon bii Odunlade Adekola, Segun Ogungbe atawon min in, ti a ba lo si odo Mista Paragon, oun lo tun maa n gba wa lamoran nkan ti a ba fe e se. Mista Paragon lo je ki n di eni to n dari fiimu lonii, ti inu mi si dun. Bi ere bi awada ni mo fi bere, ti Olorun si ba mi fi alubarika sii. Mo ranti pe ileewe alakobere ni mo ti maa n se awon nkan to jo mo ise tiata. A maa n se ileewe eko ojo isinmi ni soosi, mo maa n sere iseju marun-marun un fun won nigba yen. Nkan ta a se ta a fi dagba ni yen, ti mo fi ronu pe o ye ki n mu lokunkundun. Mista Paragon lo mu mi pade oga mi, John Babs, eni ti mo gba foomu lowo e lodun 1997.
AWIKONKO: Kini e le so pe o je adojuko latigba naa, titi di asiko yi?
FILEFUN: Ti a ba n so nipa ipenija, mi o le kaa tan, nitori pe igba kan wa tawon obi mi so pe ki n wa nkan min in se, to ba a je pe ada ni mo fe e mu lati loo darapo mo awon agbe ninu oko, nitori pe mo kan n sise nigba naa ni, mi o ri nkan kan toka sii, sugbon mo n fori tii, mo si n gbiyanju agbara mi. Mo dupe fun Olorun pe gbogbo nkan ti mo dojuko, mi o ri ijakule.
AWIKONKO: Awon ibo ni e le so pe ise tiata ti gbe e yin de?
FILEFUN: Mi o ro pe ilu kan wa lorileede Naijiria yi ti mi o tii de lori ise tiata ti mo yan laayo. Mo ti lo orileede Ghana la ti loo ya fiimu.
AWIKONKO: Awon wo ni e le so pe e jo bere ise tiata?
FILEFUN: Awa marun un la jo bere ise tiata nigba yen, sugbon meta ti ku ninu won. Awon bii Sola Odebunmi, Ganiu Ele tawon ti ku la jo bere, Omo-Olope toun ko si laarin wa mo, a jo bere naani. Odunlade Adekola, a jo bere ni. Emi ati Odunlade lo ku ninu awa marun un ta a jo bere ise tiata.
AWIKONKO: Kinni ajosepo yin pelu Odunlade Adekola ati Segun Ogungbe?
FILEFUN: Ore mi ni Segun Ogungbe, molebi kan naa ni emi ati Odunlade nitori pe omo Ekiti ni, baba ati iya Odunlade peluu baba ati mama mi, omo Ekiti kan naa ni gbogbo wa, ti a de mo ara wa daadaa. Olorun si je ki aarin wa gun rege.
AWIKONKO: Kinni ajosepo yin pelu awon osere to je omo bibi ipinle Ogun?
FILEFUN: Ajosepo to dan monran lo wa laarin wa, won ko fi oju eleyameya wo mi, won ko yo mi soto. asa ti mo maa n da, ti won fi n pe mi loruko, ‘Konfaamu ni, apaati were’, ede Abeokuta ni. Abeokuta je ilu to maa n gba eeyan mora, won kii se ilu ti won pin awon eeyan soto. Nigba ti a n se egbe osere omo bibi ipinle Ogun, iyen Ogun Indigene Entertainment Forum, gomina wa Ibikunle Amosun je ka mo pe gbogbo wa patapata ti a ti n gbe ilu Abeokuta, ta a si ti lo ju odun mewaa lo la ti di omo bibi ipinle Ogun. Gomina Amosun mu gbogbo w ape ikanna ni wa. Opo gan an ni won ko mo pe omo Abeokuta ko ni mi.
AWIKONKO: Inu egbe wo leyin wa?
FILEFUN: Omo egbe osere TAMPAN ni mi. egbe osere TAMPAN si ti gberegejige ju keeyan fowo boju pe omo egbe naa loun lo. Oludari fiimu, naa ni mo tun je olukotan, bee naa ni mo tun n kopa ninu fiimu labe egbe osere naa.
AWIKONKO: Fiimu yin ti to meloo bayii?
FILEFUN: Fiimu temi gangan ti di meta. Ikorita loruko akoko, Ofin Kokanla ni eleekeji, Koseeye ni eleeketa. Mo tun ni fiimu kan ti mo n seto e lowo, to maa too jade sita di agbelewo fawon araalu, A Ja Ma Maala ni akole e.
AWIKONKO: Opo awon eeyan ni won so pe e ko lo sileewe, se looto ni, ati pe bawo ni ti eto oloyinbo ti e n se nileese telefisan OGTV se je?
FILEFUN: Awon to ba so bee ko je ayopa, won rii so. Mi o kawe, sugbon oore ofe ni mo ri gba. Ede Yoruba ni a fi bere eto ori telefisan naa nigba ta a bere, awon kan lo so pe ki lo de ti a fi maa se e ni ti Oloyinbo. Opo awon eeyan to n pe sori eto naa lo n so pe ka bawon se e ni ti Oloyinbo nitori tawon n gbadun e. Olootu (Producer) mi wo e pe se mo le so ede oyinbo yen sa, sugbon mo dupe lowo Olorun lonii pe ti mi o ba a tii de be, won maa n duro de mi. Kii se pe mo fi n gbe ara mi ga, sugbon ni ti ipa ti mo n ko lori eto yen, Adio Konfaamu ni mo n je lori eto naa. Mo tun dupe pee to naa n kopa godo lara awon to n wo o.
AWIKONKO: Nje e tun si ni lero lati pada sileewe?
FILEFUN: Iyawo mi ti yari pe dandan ni ki n pada sileewe. Ko sigba teeyan ji, ti ko ri eeyan, eni teeyan ba fe e ri lo fe e ri. Ko sigba teeyan pada sileewe ti won ko tewo gba a. mo maa pada laipe
AWIKONKO: Awon kan gba pe beeyan ko ba soogun, ko le di olokiki nidi ise tiata. Se looto ni ati pe oju wo le fi wo o?
FILEFUN: E je ki n se apeere kan fun un yin. Nise lo da bi obinrin to n ta raisi, ti raisi e si dun, sugbon awon eeyan wa a yagbe si gbogbo agbegbe to ti n ta ounje. O digba ti won ba de be ki won to o mo pe obe e dun, bi won ba ri idoti, won ko le ya sibe. Emi o nigbagbo pe o digba to ba soogun, ki o to le ni okiki. Mo nigbagbo pe ise teeyan ba n se pelu atileyin adura, eeyan a gun oke lojo kan.
AWIKONKO: Bawo ni eto ayeye ojo ibi yi se ri lara yin?
FILEFUN: Inu mi dun gan an. Oro Funmilayo to se agbekale e si n ya mi lenu nitori pe ilu Oyinbo lo wa. Mo ni lati kii tokantokan nitori pe iyaloenu lo je fun mi. Mo sa a kan rii pe nigba ti mo ji laaro yi, lo pe mi pe ki n dide lati loo mura, o loun fe e ri bi mo se fe e mura. Mo so fun un pee mi o ri si gbogbo ibi to n gbe oro lo yen, nitori pe nkan to wa lokan mi nip e ti m ba dide, ki n gbadura, ki n si pada fun ara mi nisinmi. Igba ti mo maa dide lati silekun, iyalenu lo je fun mi pe oti ni won da le mi lori, ti won n ki mi ku ayeye ojo ibi, ti won tun korin fun mi. inu mi dun gan an.
AWIKONKO: Kinni ajosepo yin pelu eni to sagbekale ayeye ojo ibi yi fun un yin?
FILEFUN: Iyawo mi gangan ni Funmilayo Oloye. Mo si gbadura pe ki Olorun olojo oni ma f’iku ya wa. O kan maa n mu inu mi dun ni gbogbo igba ni. Leyin Olorun, Funmilayo lo tun kan nigbesi aye mi.
AWIKONKO: Amoran yin fawon ololufe e yin?
FILEFUN: Mo koko fe e dupe lowo awon ololufe mi, nitori pe bi ko ba si awon, ko le si emi, inu mi dun pe won ko tun figba kan gbagbe mi. Amoran mi nip e ki won tubo maa nife wa. ‘A Ja Ma Maala’ n bo, ki won ba mi fife gba. Ki won si ma duro de awon to n sayederu fiimu jade sita.
No comments:
Post a Comment