Ko
seni to gbo soro awon Fulani darandaran ti won tun seku pa baba agbalagba agbe
kan ti won poruko e ni Owolabi Adetona sinu oko e niluu Afon nijoba ibile
Imeko-Afon, ipinle Ogun lojo Tosde ojo kejidinlogun, osu kinni odun yi ti ko maa gbe awon odaran naa
sepe pelu awon iwa buruku ti won n hi kaakiri orileede Naijiria.
Gege
bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, won ni kii se Owolabi ti won ni aburo Oba
Afon ni nikan ni won seku pa lojo Tosde naa, won ti koko pa agbe min in, Ige
Ogun sinu oko e ni labule Asa laaro ojo naa.
Ohun
ta a gbo ni pe ko tii ju wakati merin tijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle
Amosun gbe ipinu kan dide lati dena wahala laarin awon Fulani atawon agbe
nipinle naa ni won huwa buruku yi.
AWIKONKO
gbo pe awon Fulani yi lo da maalu won wo inu oko Owolabi yiti won lojo ori e ti
le ni ogota odun to gbin efo, paki ati isu si lati jeun, ti won si ti fe e je
gbogbo oko naa tan.
Asiko
yi la gbo pe Owolabi rin sasiko to si sare loo ba won lati beere idi ti won fi
n je kawon maalu won maa je oko toun da, ti won si fe e da oun ni gbese.
Lara
awon to fisele naa to akoroyin wa leti je ko di mi mo pe awon Fulani naa ko da
Owolabi lohun, kaka ki won da a lohun, ni se ni won diro mon on, ti won si bere
sii fi ada owo won sa a.
Won ni
nigba ti won rii pe emi ti fe e jabo lara ni won sare dari awon maalu won kuro
nibe, ti won si salo ki asiri won ma ba a tu sita, bo tile je pe a gbo pe owo
ti te okan lara won.
Igbe
Owolabi la gbo pe o je kawon to n koja lo tete mo pe nkan sele ti won si sare
de be lati mo nkan to sele, iyalenu ni won lo je nigba ti won ba a ninu agbara
eje, ti won ri apa ada lara e lorisirisi.
Oku Owolabi |
Okunrin
kan to ni ka foruko boun lasiri lo je ko ye wa pe okan lara awon aburo Oba ilu
Afon ni Owolabi je, ati pe awon ebi ti so pe afi kawon olopaa tete bere igbese
lati ri won mu.
Bi
tile je pe alukoro fawon olopaa ipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi ti koko so
pe awon ko tii gbo sisele naa, sugbon to pada so fun wa pe owo ti te okan lara
awon Fulani naa, ti iwadii si n lo lowo.
O so
pe oun yoo je ka mo ibi tawon ba oro naa de lai pe, sugbon ti a ko tii gbo
nkankan titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan.
No comments:
Post a Comment