Awon Fulani Koju Ija Sawon Tisa L'Ewekoro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 1, 2018

Awon Fulani Koju Ija Sawon Tisa L'Ewekoro

Nise loro tun di bi o ko le lo ki o yago laaro ojo Tosde ojo marundinlogbon osu kinni odun yii nigba tawon Fulani to n da maalu koju ija sawon Tisa meji kan lagbegbe Onigbedu, nitosi ileese Dangote to wa ni nijoba ibile Ewekoro, ipinle Ogun, ti won si sa won nisakusa.

A gbo pe ibi ise tori da awon Tisa naa si ni won n lo laaro ojo naa, ko to o di pe won pade awon Fulani to n kawon eeyan kaakiri orileede Naijiria koju ija si won lai ni idi kan ni pato.

Inu igbo la gbo pe won ti pade won lasiko naa, ta a gbo pe won fe e fipa bawon tisa naa ti won tun je obinrin sun, sugbon tawon yen ko gba fun won, eyi ti won loo fa, ti won fi fibinu fa ada won yo, ti won si bere sii sa won bi eran.

Okunrin kan, Gbade Adeyemi to fisele naa to wa leti je ko di mi mo pe opo ise buruku lawon Fulani naa ti hu lagbegbe Ewekoro tawon si ti loo foro won to awon olopaa leti.

Okunrin naa so pe awon to wa nitosi ni won foro naa to won leti, kawon to o sare loo yoju sibe, nigba tawon si maa de be, iyalenu lo je pe inu agbara eje lawon ti ba won.

Gbade so pe.lesekese lawon ti gbe won lo si osibitu ijoba to wa ni Ifo lati gba itoju, sugbon sibe lawon tun loo so fawon olopaa Ewekoro tawon naa si ti yoju sibe.

Ogbeni Akinola Adeleke nigba toun naa n soro so pe alaga egbe awon Tisa nijoba ibile Ewekoro, Komureedi Bayo Somade atawon igbimo e ti loo sabewo si won lojo Fraide, ti igbese si ti n lo lori ona ti won le gba kapa awon Fulani naa.

O ni Sobande bu enu ate lu iwa tawon Fulani naa n hu kaakiri orileede yi, nitori pe emi maalu ti won n da jo won loju ju emi awon eeyan lo, tijoba ko si wa nkan se si.

Gbogbo igbese lati ba agbenuso awon olopaa, Abimbola Oyeyemi soro lati fidi isele naa mule lo ja si pabo, nigba ta a pe foonu titi ti ko gbe, ti ko si tii da atejise wa pada titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI