Bi kii
ba a se ifura tawon osise kootu Isabo niluu Abeokuta ni si okunrin kan ti won
pe oruko e ni Omoniyi Vacoster, eni ti won lo n fise ati aso agbejoro lu awon
eeyan ni jibiti owo, bo ya ki ba mai ti ronupiwada dasiko yii.
Ojo Aiku
Sande ojo kerin osu to koja yi ni agbenuso fawon olopaa ipinle Ogun, Ogbeni
Abimbola Oyeyemi firoyin Omoniyi to AWIKONKO leti, nibi to ti so pe okunrin naa
ti n ka boroboro pe ki won se oun jeje, atije lo sun oun de be.
AWIKONKO
gbo pe ojo ti pe ti Omoniyi ti maa n gba ise lowo awon eeyan, to si maa lo si
kootu lati jeri gbe won, lai mo pe ko tii kun oju osuwon lati di eni ti won le
maa pe ni agbejoro, depodepo pe yoo gba ise.
Okan
lara awon omo egbe agbejoro nipinle Ogun, Arabinrin Omomehin Oluwatoyin la gbo
pe o fura si Omoniyi wi pe kii se ara won, ti won ko si tii fun niwe eri gege
bi agbejoro, ko to o di pe o loo fejo e sun DPO olopaa to wa ni Ibara, Abeokuta
tawon yen si bere igbese lati sewadi e.
Omomehin
tun so fawon olopaa pe aimoye igba lawon ti ri Omoniyi kaakiri inu kootu, nibi
to ti n gbejoro fawon eeyan, eyi to mu kawon bere iwadii lori e, tawon si rii
pe won ko tii pe segbe awon agbejoro.
Lesekese
ti DPO naa ti gbo lo ti ran Ogbeni Dada Olusegun to je igbakeji e lati lewaju
awon olopaa ti yoo lo mu okunrin naa, ki won si sewadi e, towo si te e lojo
Tosde to koja yii.
Nigba
to n soro, Omoniyi so pe looto loun ko tii di agbejoro, bo tile je pe oun ko
eko nipa ise agbejoro nile iwe giga Yunifasiti, sugbon toun ko tesiwaju lati lo
sileewe ti won yoo ti so oun di ojulowo agbejoro.
O
tesiwaju pe ki won foriji oun nitori airikansekan lo je koun gbegba agbejoro
lati ma se gbagbe awon eko toun ko nileewe, bo tile je pe o si ni lokan lati
kawe sii, koun si gba iwe eri nidi ise naa.
Ahmed
Iliyasu to je Komisana olopaa ti wa a pase pe ki eka ileese won to n ri si iwa
odaran, iyen State Criminal Investigation and Intelligence Department, SCIID
tesiwaju lori lori ejo naa, ki won si rii pe won foro wa a lenu wo daadaa lati
tun mo iru eeyan to je lawujo.
No comments:
Post a Comment