Adajo Ju Ramoni Sewon Odun Meji Nitori Eran Agbo To Ji Gbe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 1, 2018

Adajo Ju Ramoni Sewon Odun Meji Nitori Eran Agbo To Ji Gbe

Iyalenu loro okunrin eni odun metadinlogoji (37) kan, Ramoni Bello si n je fawon to gbo nipa bi adajo ileejo Majisireeti to wa niluu Ota ipinle Ogun se juu sewon odun meji gbako nitori eran agboole ti won loo ji gbe lai fi aaye sile wi pe bo ya ko san owo itanran lojo Tusde ose to koja yi.

Gege iroyin naa se to wa lowo, a gbo pe eran agbo ti owo ko din legberun marundinlogorin (75,000) naira ni won so pe Ramoni ti won ni ojule kerinla, adugbo Bamidele, Ota lo n gbe loo ji gbe lojo ketala osu yi ni nkan bii aago marun un aabo afemojumo.

Eni to ni eran naa, Ogbeni Kehinde Yekinni ta a gbo pe agbegbe Bible College Bus-stop Ota lo n gbe, nibe si ni Ramoni ti loo ji eran agbo naa la gbo pe o loo foro naa to awon olopaa Ota leti nigba ti ko ri eran e lasiko to fe e fun lounje laaro ojo naa, tawon olopaa si bere igbese lati sewadi e.

Ojo keji la gbo pe asiri e tu sawon araadugbo lowo, ti won si tete loo ranse sawon olopaa lati wa a muu.

Lesekese tasiri Ramoni ti tu lo ti bere sii bebe wi pe ki won se oun jeje nitori pe ebinto n pa oun lo sun oun de be, toun ko si ni ona abayo min in lati jeun, ati lati fawon ebi oun lounje je.

Gbogbo ebe ti won ni Ramoni be la gbo pe ko wo awon olopaa ati Kehinde to ni eran naa leti, ti won si loo foju bale ejo Majisireeti, ko si le gba idajo to to sii.

Bo tile je pe nise loro yi pada nigba ti adajo ile ejo naa, Ogbeni S.O Banwo so pe oun ko bii faaye sile fun lati san owo itanran pelu gbogbo ebe to be, to si gba pe oun jebi lojo naa.

Agbejoro awon olopaa, Ogbeni Chudu Gbesi to tako Ramoni niwaju adajo naa so pe ese to se tako iwe ofin odaran tipinle Ogun, todun 2006.

Eyi gan an lo fa a ti Banwo fi so pe ko loo fi ewon odun meji gbara pelu ise asekara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI