Oba Halidu Adedayo Olaloko, Agura
tiluu Gbagura ti so pe eeyan ti ko nise lapa ko le je oye to ba kere ju, paapaa
oye Balogun laafin, nitori pe ko ni bojumu ki oloye ma le se awon eto to ba ye
ki iru oloye bee se laafin.
Oba Agura |
Kabiyesi so pe aye atijo ni won ti
n fi awon ti ko nise lapa atawon eeyan lasan je oye laafin, sugbon pelu olaju
to de lasiko ta a wa yi, eeyan lasan ko le je oye mo laafin, paapaa eni ti ko
ba ti lowo lowo, nitori pe eni ti won ba fi je oye gbodo je eni to lowo lowo
lati se awon eto to ba ye ko se laafin ati lawujo to ti je oye.
Bee lo so pe oloye nikan lo maa n
ku, sugbon ti oye wa titi lai, ati pe bi oloye kan ba ti papoda, o di dandan ki
won yan oloye min in lati di oye naa, eyi lo so pe o lo nibamu pelu bi won se
yan Oloye Biobaku gege bi Balogun tuntun fun ilu Ijaye Obirinti lati ropo
Balogun ana to papoda.
Kabiyesi tesiwaju pe bi won ko ba
tete yan oloye min in lasiko to ba ye, esinsin-kesinsin maa ba le oye naa,
tawon eeyan yoo si maa ja si lati je e, eyi to si le sakoba fun ilosiwaju ati
idagbasoke ilu naa.
Ninu oro e, o so pe “Gbogbo wa la
mo wi pe oye kii ku, bi oloye kan ba ku lonii, elomin in a tun je. Ko si oloye
ti ko le je oye mejo, nitori pea aye si sile fawon oloye lati je oye to ba wu
won.
“Abiola lo koko bere e, bo se je
oye l’Egba, bee lo je n’Ibadan atawon ilu min in kaakiri. Mi o lodi si eni ti
mo fi je Balogun Ijaye Obirinti lonii, emi to ba si je oye lo maa lo o lalope.
Balogun tuntun |
“Eni to maa tun ilu se lo n je
Balogun. Bi won ko ba si tete je e, esinsin-kesinsin yoo ba le e. Mi o fe ko ma
a lo so kaakiri wi pe oun ti je oye Balogun lai je pe mo jokoo laarin eyin ilu
lati fi onte si, ki n si so fun un yin wi pee mi ni mo fi je Balogun, ki
awuyewuye ma ba a teyin e yo lojo iwaju.
“Ko seni ti ko le je oye Balogun,
sugbon eni to ba maa je gbodo sise de be, ko to o di pe won yan an sipo.”
Nigba to n soro, Balogun Ijaye
Obirinti tuntun naa, Oloye Biobaku Bakare dupe lowo Oba Agura tiluu Gbagura fun
anfaani to foun lati je oye Babanla oun, ati pe oun ko ro o ti tele wi pe oun
le je oye naa, bo tile je pe kii se oye akoko toun maa je ni Balogun toun sese
je naa.
O ni oye naa dun mo oun ninu pupo
nitori oye ilu oun ni, ati pe ilosiwaju, alaafia ati isokan ilu naa lo je oun
logun, pelu bi oye naa tun se je oye asiwaju ilu, oye to je pe oye to n wa
alaafia ati ilosiwaju ilu ni.
No comments:
Post a Comment