Eyi Ni B'owo EFCC Se Te Awon Omo Yahoo Meedogun To N Seso Ni Sagamu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, February 7, 2018

Eyi Ni B'owo EFCC Se Te Awon Omo Yahoo Meedogun To N Seso Ni Sagamu

Bo tile je pe ajo EFCC ti so pe a fi kawon gbe awon odomokunrin meedogun (15) tojo ori won ko tii ju odun merinlelogun lo, tasiri won tu lojo Abameta Satide to lo lohun niluu Sagamu wi pe won ko nise meji ju ise Yahoo lo lo sile ejo lati gba idajo to to si won, si be, titi di bi e ti n ka iroyin yi lenu si fi n ya opo awon to wa nitosi ibi ti won ti loo ko won nitori taa tun gbo pe awon omo tojo ori won ko ju odun metadinlogun lo naa wa lara won peluu.

Adugbo Sotubo ati Awolowo nitosi oja igbalode Awolowo la gbo pe awon ajo to n gbogun ti si se owo ilu mokumoku, iyen EFCC eka tipinle Eko ti loo ko won leyin tawon kan lo ta won lolobo wi pe awon odomokunrin naa n da alaafia adugbo laamu, tawon olopaa ko si ri nkan se sii.

Oruko won ni: Osidipe Olatunbosun ati Awe Ayodele ti won je omodun merinlelogun (24); Awe Abimbola Ireti to je omodun metalelogun (23); Adeyemi Tiwatope, Odeyemi Olawale, Nike Afolabi Olaiya, Yusuf Aliu Oluwafemi ati Damilola Fatona ti won je omo ogun odun (20).

Awon to ku ni Tosin Adesanya, Afolabi Lekan ati Adeyemi Gbadebo ti won je omodun mokandinlogun (19); Aliu Lukman ati Shonubi Adetola ti won je omodun mejidinlogun (18) peluu Adeyinka Bello ati Adewale Babatunde tawon je omodun metadinlogun (17).

AWIKONKO gbo pe yato sawon omo towo te yii, asiri babalawo won, Adesanya R. Olaoluwa naa tu, bo tile je pe lesekese tiroyin ti kan sii loun ti na papa bora ni ti e, sugbon tawon ajo EFCC si n wa.

Lara awon nkan ta a gbo pe won ba ninu ile ti won gbe ni igba, poosi, orisirisi oogun, seeni olowo nla, kaadi ero ibanisoro (sim cards), moto bigini olowo nlan mefa, awon ero komputa alagbeka (laptops), foonu olowo nla lorisirisi, awon ayederu iwe ti won yi atawon nkan min in ti won fi n sise.

Won ni awon araadugbo ti won ti fejo won sun awon olopaa to wa niluu Sagamu pelu igbesi aye ti won n gbe, ti won si tun n da alaafia awon araadugbo naa laamu, sugbon ti won lawon olopaa ko ri nkan se sii, lo je ki won gba ileese EFCC to wa l’Ekoo lo lati loo fi to won leti.

A gbo pe se lawon omo yi kan n fi ise Yahoo boju ni, osole ni won se, eyi ti won n pe ni Yahoo-Plus, to si je pe awon omobinrin, paapaa awon omobinrin ti won ba pade lori ero ayelujara ni won maa n lo lati fi seso, ki owo wole fun won.

Bee la tun gbo pe, won tun n lo anfaani lati lu awon eeyan ni jibiti owo lati ori foonu, eni ti won ba pe lori foonu, won a fi oogun senu ba a soro, teni naa yoo si kowo fun won.

Lara awon to b’AWIKONKO soro je ko ye wa pe, kaka kawon omo wonyii maa bebe lojo tasiri won tu, seni won tun n rerin bii pe awon fe e lo gbadun lodo awon ajo EFCC ni, tawon ko si ni pe e de, nitori ti won gba pe ko si nkan towo won ko le se fun won.

Ni bayii, ohun tawon kan n so ni pe kijoba gba won, ki won ma je kawon omo naa wale mo, nitori pe bi won ba fi won sile, won a tun se ju nkan ti won ti n se bo lateyin wa lo, ti ajo EFCC naa ti seleri wi pe dandan ni ki won foju won bale ejo lai pe, leyin ti iwadii won ba parii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI