Bi iroyin to n lo kaakiri igboro
bayii nipa okan lara awon agba gbajumo sorosoro ori redio, Babatunde Okunade
tawon eeyan mo si Omoba ba fi le je otito wi pe Booli ati epa lo tun n ta
bayii, a je pe a fi kawon omo egbe sorosoro tete wa nkan se soro e.
Gege bi iroyin to te AWIKONKO
lowo lai pe yi se so, won ni Omoba tawon eeyan tun n pe ni Alabi Okunmase lawon
eeyan ri nibi to ti n fi abebe fe ina Booli leyin soobu tuntun ti Gomina ipinle
Ogun, Ibikunle Amosun sese ko si oja Omida niluu Abeokuta.
Awon to gbe iroyin naa si wa
leti je ka mo pe beeyan ba ri Omoba nibi to ti n ko ina mo awon booli lojo naa,
yoo mo pe ko mu ise naa loro ere rara, ati pe odo obinrin kan ti won n pe ni
Iya Waidi lo ti lo n ta a.
Opo awon to mo Omoba mo ise
redio, paapaa to tun n se eto kan lori redio Paramount 94.5 ni gbogbo ojo
Abameta Satide laarin aago mokanla aabo aaro si aago mejila osan, eto naa to pe
ni “Lat’inu Iwe Mimo” ni won beere wi pe ki lo le fa a to fi je pe igba Booli
ni okunrin naa tun gbe bayii.
Ko kuku je tuntun pe kawon to
gbajumo maa se awon ise to n ya awon to feran won lenu, bi e ko ba gbagbe, odun
to koja ni Iyabo Ojo naa si ile ounje ti won ti n ta Amala siluu Eko, ti
Odunlade Adekola naa si soobu ti won ti n gerun siluu Abeokuta.
Sugbon eyi ti Omoba Okunade se
yi lo tun je kayeefi fawon to rii, ti won tun so pe ko gbe oju pamo fawon to
mon on, to sit un n je ki won mo pe idi ise eni la ti n mo ni ni ole (lazy).
Ibeere tawon eeyan n beere bayii
ni pe, ki lo le fa a to fi je pe igba Booli ni Omoba, iyen Alabi Okunmase gbe,
nigba tawon ise to dun n ri mo eeyan bii ti e wa nigboro, sugbon ta a gbo pe okunrin
naa so pe ise to ba wu eeyan lo le se, ti ko si seni to le mu enikeni si ise to
bay an laayo.
No comments:
Post a Comment