Bi
kii ba a se pe awon eleyinju aanu tete gba okunrin kan eni odun mejilelogoji
(42) ti won poruko e ni Ajiboye Emmanuel Olusola ti won ka Oku omo kekere mo
lowo lojo Fraide ose to.lo lohun ni gaaraji Sapade nipinle Ogun, o see se ko ti
dero orun alakeji nitori pe die lo ku ki won dana sun un.
Ohun
ta a gbo ni pe ipinle Kwara ni Emmanuel ti n bo, to si n lo siluu Eko ko too di
pe asiri e tu sawon araalu lowo lakoko to fe e moto ni garaaji Sapade, ti won
si pariwo e sita.
Gege
b'AWIKONKO se gbo, ni bo tile je pe ko seni to fura sii pe oku omo lo wa ninu
baagi to gbe dani nitori ona to fi gbe e , sugbon nigba ti oku naa bere sii
run, ti oorun naa si ti koja afarada fawon eeyan to wa ninu moto to wo ni won
pariwo lee lori wi pe ko bo sile.
Ka
ni o mo pe asiri oun maa pada tu ni, o see se ko ti bo sile lati wa ona min in
to maa gba de ilu Eko to n lo nigba tawon n pariwo lee lori wi pe ko lo gbe
nkan to wa lowo e sonu sinu igbo, toun naa si sori kunkun.
Nigba
tinwon beere lowo e pe ki lo wa ninu baagi naa, nkan to so fun won ni pe ajeku
ounje lo wa ninu e, ati pe oun fe e gbe lo fawon eran oun ni, awon to fura sii
ni won so fun un pe ko je kawon ye e wo, sugbon to ni ko si nkan to jo.
Nigba
ti won rii pe okunrin naa ko fe e bo sile, ti ko si fe kawon eeyan wo nkan to
wa ninu e, ni won ba baa se lagidi, ti won si fa baagi naa ja mo lowo, nigba ti
nkan to wa ninu e maa fi bo sile, lo ba di oku omo kekere.
Iyalenu
lo je fawon to wa nibe ti won si bere sii luu nilukulu wi pe okan lara awon
gbomogbomo to maa nnji omo gbe fi soogun owo ni, ati pe o see se ko je pe
omolomo lo lo ji gbe lati loo ta a fawon to ran nise.
Nigba
ti won beere lowo e pe nibo lo ti rii, nkan to so ni pe omo oun ni, ati pe ose
naa lo ku, ko sii sibi toun le sin in si, lo je koun pinu lati loo sinku e silu
Eko, nitori pe Offa loun ti n bo.
Emmanuel
so pe kasiri oun ma baa tu lo je koun gba Sapade lati lo silu Eko, sugbon
gbogbo bo se n soro naa ni won so pe iro lo n pa, ati pe awijare lori asan lo n
wa.
Lesekese
la gbo pe awon to wa nibe ti bere sii luu, ko to o di pe awon kan tete ranse
sawon olopaa to wa ni Isara lati fi to won leti, tawon naa ko si foro naa para
ki won too lo.
Alaye
ti won lokunrin naa tun se fawon olopaa ni ko te won lorun, ti won si gbe e lo
si tesan won lati loo tesiwaju nipa iwadii won.
Agbenuso
fawon olopaa, Abimbola Oyeyemi je ko di mimo pe Komisana won, Ahmed Iliyasu ti
gbo soro naa, o si ti pase pe kawon olopaa to n ri soro apaayan gba ise iwadii
naa se.
No comments:
Post a Comment