Paseda fe itosona Olorun lori ibo odun 2019 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 16, 2018

Paseda fe itosona Olorun lori ibo odun 2019

Otunba Rotimi Paseda to je adije sipo gomina ipinle Ogun lodun 2015 ti so pe itosona Olorun loun n wa lori ibo odun 2019.

O soro yi lakoko to n waasu gege bi ojise Olorun niluu Ijebu Ode lai pe yi nibi to ti so pe gbogbo eeyan lo ni igbagbo, sugbon o ni bi onikaluku se n lo o, ati pe ireti se pataki pupo nigbese aye eeyan.

Inu soosi Ridiimu Divine Covenant Assembly to wa ni adugbo Fakoya Oregun, Ikoto nilu Ijebu Ode ni isoji Ireti naa ti waye nibi tawon omoleyin Kristi ti waasu, ti won si tun fadura jagun.

Nigba to n waasu, Paseda so pe gbogbo eeyan lo ni igbagbo nitori pe ti ko ba ri be e, ko seni to maa wa nibi isoji naa nitori pe igbagbo ti won ni lo je ki won gbera lati wa nibe.

O tesiwaju pe igbagbo lai si ireti, ni se lo da bi oko ti ko si ero ninu e, ati pe nigba ti eeyan ba padanu ireti, o ti padanu ohun gbogbo.

Ninu oro e siwaju sii, Paseda so pe "Olorun to da eeyan ko seleri aye ti ko ni isoro ati adojuko, sugbon opo wa la ti padanu igbagbo wa ninu ile, ofiisi, ayanmo, ebi, paapaa julo ninu awon olori wa to n sejoba.

"Eni to ba sare ije ireti pelu igbagbo nikan lo maa de ebute aseyori. Mo fe ro yin pe ki e gbe ireti yin sinu baagi nitori pe oun gan an ni ojo iwaju, ki e si sare igbagbo pelu e titi digba ti e maa fi de ebute ogo."

Nigba to n soro nipa ipinu e lori isoji naa ti won pe akori e ni Isoji Ireti, o ni kii se ti oro oselu rara, nitori pe Olorun lo ran oun, oun ko si le se nkan ti Olorun ko ba pa lase foun.

"Mi o ti e tii pinu lati bere sii soro lori oro oselu nitori pe iranse Olorun ni mi, mo si gbodo koko se ife Oluwa  to ran mi nise si awon eeyan. Gbogbo eeyan lo nilo ireti."

Saaju akoko yi ni Pasito Ayo Ayanfe Olutola ti koko waasu lori akori to pe ni "Igbala Je Dandan", nibi to ti so pe gbogbo eeyan lo nilo igba la kuro lowo ese awon babanla wa, iyen Adamu ati Eefa.

O sapejuwe igbala gege bi irapada kuro lowo agbara ese, ati itusile kuro ninu awon nkan ti a jogun ninu ogba Edeni. Bee lo so pe igbala je nkan pataki ninu eto Olorun fun eeyan.

Nigba to n sapejuwe ipele ti iku pin si, o ni ona meta ni iku pin si; ona kinni in ni iku ti emi, eekeji ni iku ti ara nigba ti iku keta je iku ti ayeraye.

Pasito Ayanfe so pe pataki idi ti won fi gbe isoji yi kale ni wi pe Olorun fe e gba opo awon eeyan sile lowo ogun to n ba won finra, toun si nigbagbo pe won yoo ri aanu Olorun to se iyebiye gba.

Bakan naa ni Wolii J.O Jegede fi adura agbayipo ja awon eeyan to wa nibi isoji naa gba kuro lowo ogun aye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI