Nitori foonu; Ranti gun Farooq pa lojo keresimesi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 4, 2018

Nitori foonu; Ranti gun Farooq pa lojo keresimesi

Opo awon to gbo sisele buruku naa ni won n so pe bebe pe kawon olopaa ma je ki odomokunrin eni odun mokanlelogun (21), Israel Oluranti ti won so pe o gun Farooq Olusegun pa lojo odun keresimesi lo lai se idajo fun labe ofin.

Gege b'AWIKONKO se gbo, adugbo kan ti won pe ni Ope-Ilu lagbegbe Agbado nijoba ibile Ifo nisele aburu naa ni sele nigba ti won so pe foonu ti Farooq eni odun mejidinlogun (18) n wa lo da wahala naa sile.

A gbo pe iwaju ita ile ti Farooq n gbe lawon odo ti n sayeye odun keresimesi lojo Aje Monde ose to koja lo yi, ti won forin orisirisi da ara won laraya.

Awon to gbe iroyin naa s'AWIKONKO leti je ko ye wa pe Farooq n saaji foonu e lowo nibi ti DJ to n sere fun won wa, sugbon sadede ni won so pe Farooq bere sii wa foonu e, to si wo gbogbo ayika, ti ko rii.

Enikan la gbo pe o ta Farooq lolobo pe ko loo bere lowo Oluranti nitori pe oun lo de be, toun naa si loo beere lowo e nibi to tinn mu oti lowo pe se ko ba oun ri foonu, nitori ti won so pe oun lo de be.

AWIKONKO gbo pe kaka ki Oluranti farabale lati salaye pe oun ko mu foonu, nise lo gba oro naa sodi to si so o di ariwo, kawon eeyan to bere sii bee.

Ere lawon eeyan koko pe e lai mo pe oti to n mu lowo ti wo o lara, to si ki okan lara awon igo oti to ti mu tan mole, to si law mo irin kan, ko too di pe o fi kun Farooq laya.

Ariwo bi Oluranti se gun Farooq nigo yi lo je kawon eeyan ti ko mo nkan to n sele tele gbera lati loo, sugbon nigba ti won maa ri de be, akuko ti n fe e ko leyin omokunrin Farooq.

Ohun ta a gbo ni pe lesekese ni oju Oluranti ti wale nigba to rii pe emi ti fe e jabo lara Farooq, to si fe e na papa bora, tawon to wa nibe ko si je ko lo, ko too di pe won lo ranse pe baba ati mama Farooq lati fi to won leti.

Awon agbaagba to gbo soro naa ni won so fun baba Farooq, Ogbeni Kolawole Abiola pe ki won mu Oluranti lo tesan olopaa lati fi to won leti, bee ni won tun sare gbe Farooq lo si osibitu to sunmo won lati doola emi e.

Won ni ko ju ogbon iseju ti won gbe Farooq de osibitu lo dagbere faye, eyi gan an lo tun ki baba Farooq fesun apaayan kan Oluranti lodo awon olopaa ni tesan ekun Agbado.

Bee la tun gbo pe Farooq ati Oluranti ti jo figba kan ni gbolohun aso tele, ti won si tun jo leri iku sira won, ko too di pe ojo buruku naa waye.

Nigba ton fidi oro naa mule, Agbenuso fawon olopaa ipinle Ogun so pe lesekese ti Komisana won ti gbo lo ti pase pe ki won maa gbe e bo ni OLU ileese won to wa ni Eleweran niluu Abeokuta, to pase pe ki won gbe loo si eka ileese won to n ri soro apaayan lati tan imole sii.

Bee lo so pe Komisana won, Ahmed Iliyasu ti seleri wi pe Oluranti yoo foju bale ejo leyin tise iwadii won ba pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI