...Oba olusona ni Amosun
Omoba Adewole Adejuwon David to je okan lara awon to n foju sona lati dupo omo ile igbimo asofin nipinle Ogun ti so pe oun ko nii gba ki igbakeji Aare teleri lorileede Naijiria, Atiku Abubakar di Aare orileede yi lodun 2019.
Omoba Adewole Adejuwon, ACAD |
Omoba Adewole tawon eeyan tun n pe ni ACAD soro yi lojo Wesde to koja yi niluu Sagamu lasiko to n gbawon igbimo fidihe egbe awon oniroyin ori ero ayelujara, National Association of Nigerian Bloggers, NANB lalejo.
O so pe bi gbogbo eeyan ba n so pe awon fe e dupo Aare orileede Naijiria, ko to si Atiku Abubakar nitori pe ko ni nkan meji to fi n soro bi ko se iwa ajebanu lo, to si han sopo awon omo orileede yi, paapaa lasiko toun ati Aare teleri, Oloye Olusegun Obasanjo jo se ijoba lodun 1999 sodun 2007.
ACAD so pe nigba ti Atiku Abubakar gbe apoti lati dupo Aare lodun 2017, ati pe nigba o wa nijoba, aimoye igba ni Baba Obasanjo ti tu awon asiri iwa ajebanu to wa lowo, ti ko si fe e ki orileede yi ni ilosiwaju, pelu bo se n fa ogo orileede yi seyin, toun naa ko si so nkankan lati tako awon esun naa.
O tesiwaju pe ko seni ti won maa fesun kan ti ko bii da esi oro pada lati so pe owo oun mo, ko si oro lati jeri gbe ara e, sugbon ti Atiku ko so ohunkohun.
Bee lo seleri wi pe eje to ba ku lara oun loun yoo fi se ipolongo lati tako ipinu e lati di Aare orileede yi bi asiko ba to fun ipolongo idibo odun 2019 ti gbogbo eeyan n foju sona fun.
Bakan naa lo tun so pe bi nkan ba fi le yi pada, ti Atiku Abubakar di Aare lodun 2019, oun yoo ko gbogbo molebi oun kuro lorileede Naijiria, toun yoo si gba orileede min in lo lati lo maa gbe nitori pe Atiku ko le je Aare oun lailai.
Omoba Adewole je ko di mi mo pe ko si alatako to le idibo tako Aare Muhammadu Buhari ninu idibo odun 2019 nitori pe ko tii seni to kun oju osuwon lati di Aare lodun 2019 naa.
O ni bo tile je pe Aare Buhari n gbiyanju gbogbo agbara lati satunse yo ye lorileede Naijiria, sugbon to je pe awon to ko mora ni isoro to ni, nitori pe awon ninwon n fa owo aago e seyin latari iwa ajebanu.
O ni orileede yi n saisan koja oju tawon eeyan fi n wo o, nitori pe orileede Naijiria je orileede kan to je pe awon odo (Youth) ko mo nkan ti won le se mo, ti won si ti n so ireti won nu wi pe nkan si maa pada bo sipo.
Okunrin naa tesiwaju pe isoro kan soso ti Aare Buhari ni ninu ijoba e ni ti awon ileri aseju to se fawon omo Naijiria lasiko ipolongo ibo odun 2015, ti ko si tii se ju ida meta ninu mewaa lo.
O ni ti ki ba a se pe Buhari se ileri to po ni, awon omo orileede ko nii ronu lo sawon nkan to ti seleri e, ti ko si tii se, toun si nigbagbo pe o maa se e to ba wole eleekeji.
Bakan naa lo sapejuwe gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun gege bi Oba olusona latari awon ise idagbasoke to ti se kaakiri ipinle naa, eyi tawon gomina to ti je saaju e ko ronu nipa e ri.
O ni ko si ilu teeyan maa de nipinle Ogun, ti ko nii ba afara oloke nibe, ati pe yato si afara oloke, opopona to tobi ni gomina Amosun tun se sibe lati le je kipinle Ogun dun un wo loju awon eeyan lagbaye.
Nigba to n soro lori ipinu e lati gbe apoti omo ile igbimo asofin to n soju ekun Sagamu, o ni ife ati ilosiwaju agbegbe oun loun n fe, nitori pe latigba toun ti wa nileewe giga loun ti je Aare egbe awon akekoo, toun si ti lewaju awon iwode atunse kaakiri orileede yi, lati ja feto awon eeyan.
O ni awon nkan toun si n se lasiko yi ni pe oun si n rin awon irin kan, toun si tun n se awon ipade abele kan lati ri awon agbaagba nidi oselu lati wa ojurere won, toun si mo pe oun yoo ba ojurere won pada pelu ogo Olorun.
No comments:
Post a Comment