Se won lomo iya meji
kii rewele ni, sugbon oro Nkoenye Jibunor ati Paul Jibunor ti yato gedengbe
nitori ti won so pe won ko nise meji ju ki won maa fipa bawon obinrin sun
kaakiri igboro lo, ti won si tun n lo anfaani e lati maa jawon eeyan lole.
Gege bi iroyin to te
AWIKONKO lowo se so, a gbo pe ojo kokanlelogbon osu kejila odun taa sese lo tan
yi la gbo pe asiri won tu sawon olopaa ipinle Ogun lowo nigba ti won ni
odomobinrin kan, Ijeoma ti won fipa ba sun lojo kokandinlogbon osu naa loo foro
won to awon olopaa leti, tawon yen naa ko si foro naa sere kinwon to gbe igbese.
Nkoenye ti won lomo
odun mejidinlogbon (28) ni ati aburo Paul ti won lomo odun metalelogun (23)
loun ati eni keta won ti won niyen ti na papa bora la gbo pe won maa n lo moto
kan ti won pe ni Uber lati maa fi bays awon omobinrin je kaakiri.
A gbo pe ni se ni
won n lo moto naa bi moto ti won fi n ko ero, sugbon to je pe ode obinrin ti
won maa ba lo po, ti won si tun maa ja lole ni won fi n se.
Ohun ta a gbo ni pe
agbegbe ojubo Fela to wa ni Oregun nipinle Eko ni Ijeoma ti dawon duro pe oun n
lo si agbegbe Ojodu Abiodun, ti won si jo duna dura.
Iyalenu lo je fun
Ijeoma nigba to rii pe won ya wo koro kan ki won too debi to n lo, to si beere
pe nibo ni won n gbe oun lo, ti ko seni to da a lohun, nibe lo ti bere sii
fura, sugbon ti ko mo nkan to le se.
AWIKONKO gbo pe bi
won se de iwaju ile akoku kan ti won ti maa n sise ibi won ni won ba a fipa wo
Ijeoma bo sile.ninu moto ti won si woo wole ki won too fipa bo aso e, ti won si
bere sii gba kini abe won mon on labe.
Awon meteeta la gbo
pe won mu nnkan labe Ijeoma, ti won si tun jaa lole awon eru to.ko sinu baagi
to gbe dani ko too di pe won salo.
Lesekese la gbo pe
Ijeoma ti gba tesan olopaa ekun Ojodu Abiodun lo lati loo fejo sun. Nigba
tasiri won maa pada tu, Ijeoma lo tun kefiri won ladugbo Adebayo ni Ojodu kan
naa, to si sare tawon olopaa lolobo wi pe oun ti rii won.
Ka ni awon olopaa
lo.iseju kan si kinwon too gbera ni, o seese ko je pe awon meteeta ninwon maa
salo, sugbon ti won pada ri meji mu lara
won.
Ohun ta a gbo ni pe
bi won se mu won tan, lawon eeyan bere sii yoju wi pe odaran paraku ni won
nitori tawon mon won, sugbon tawon ko le foro won to olopaa lowo nitori ti won
maa n dunkoko pe awon yoo pawon ni bi won ba so.
Nigba tawon mejeeji
n soro ni won je ko ye awon olopaa wi pe oro awon kii soju lasan, o see se ko
lowo aye ninu sugbon tawon ko mo ona min in lati maa ri owo.
Awon mejeeji ni won
jewo pe o ti le lodun meji tawon ti n sise naa, tawon ko si.le soniye obinrin
tawon ti fipa ba sun, tawon si tun ti ja lole.
Nigba to n jeri sii,
Abimbola Oyeyemi to je agbenuso fawon olopaa so pe bo tile je pe iwadii
sinn lo lati mu enikan toku won to salo, sibe orisirisi eru ti won ti fipa gba
bii seeni, aago owo ati foonu ni won ri gba lowo won.
O ni Komisana won ti
pase pe kawon olopaa to n ri soro awonnodaran,iyen SCIID tesiwaju ninu iwadii
lati rii pe won mu eni to salo naa, ki won si foju won bale ejo lai pe.
No comments:
Post a Comment