Asiri ogbologbo adigunjale tu sawon olopaa lowo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 4, 2018

Asiri ogbologbo adigunjale tu sawon olopaa lowo

Pakopako ni Opeyemi atawon ore e meta ti won ni won ko nise meji ju ise adigunjale lo ati pe won tun maa n gbe igi dana gba moto lowo awon eeyan to ba n koja lo lopopona n wo logba olopaa nigba towo olopaa te won.

Opeyemi Okegbenro, Israel Adams, Ali Chibike ati Patrick Nwandagba poruko awon odaran naa ti won so pe ni nnkan bii ago mokanla aabo ale ojobo Tosde ose to koja lakoko ti won gba moto jiipu Lexus RX 330, ti nomba e je  KSF 509 CV lowo okunrin kan lagbegbe Odogbolu loju ona Sagamu si Ijebu Ode.

Gege b'AWIKONKO se gbo, won ni orisirisi moto lawon odaran yi fi igi ti da duro lojo naa, ti won si ti jawon eeyan lole eru won pelu ibon lowo.

A gbo pe lara awon ti won ja lole lo te olu ileese olopaa laago lati foro naa to won leti, ko too di pe Komisana won, Ahmed Iliyasu ranse pe oga awon SARS lati tete gbera loo koju won.

Nigba ti won maa de be, a gbo pe won sese gba moto jiipu Lexus naa tan ni, ti won si ti fe ma a salo, sugbon bi won se ri awon olopaa la gbo pe won ti koju ibon si won tawon yen naa si koju ibon pada si won.

Siwaju sii la gbo pe nigba tawon odaran naa rii pe agbara won ko fe e ka awon SARS naa mo, lo mu ki won pinu lati na papa bora, sugbon ti ori tako awon merin ninu won, tawon to ku si salo.

Nigba to n jeri sii, Abimbola Oyeyemi to je agbenuso je ko di mimo pe laaro ojo naa, awon odaran naa yinbon fawon olopaa meji, Oluwatobi Iwata ati Samuel Olatunji nigba tawon yen loo kolu won nibi ti won ti loo jale.

AWIKONKO rii gbo pe ki won to o gbe Samuel Olatunji de osibitu, elemi ti gba a, akoko ti ko leyin omokunrin e, latigba naa la gbo pe ileese olopaa ti bere sii wa won ko too di pe asiri won pada tu lale.

O so pe yato si pe awon gba moto Lexus naa pada feni to bii, tawon si tun gba awon nnkan bii ibon meta otooto, ota ibon lorisirisi lowo won, sibe iwadii si n lo lati ri won mu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI