Asiko ti to fawon eeyan lati maa mu oti bo se wu won – Ayinla Kazeem - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 30, 2018

Asiko ti to fawon eeyan lati maa mu oti bo se wu won – Ayinla Kazeem

Alase ati Olusaduile ileese Seakam Global Resources to n se oti Bajinatu, Alaaji Ayinla Kazeem ti fokan awon omo orileede Naijria bale wi pe asiko yi gan an lawon eeyan nilo lati maa mu oti bo ba se wu won, nitori pe pataki awon oti tileese won n se lasiko yi ni lati je ki awon eeyan wa ni ilera pi pe.

Alaaji Ayinla Kazeem
Alaaji Ayinla Kazeem lo soro yi niluu Eko nigba to n b’AWIKONKO soro ni gbagede ayeye Blue Roof to wa ninu ogba ileese telifisan LTV8 to wa n’Ikeja lojo Sande to koja yii nibi ayeye ojo-ibi aadota (50) odun Alaaji Wasiu Alabi Odetola Pasuma tawon omo egbe ololufe e, Pasuma Fans Club sagbekale e.

Nipa oro to n lo nigboro wi pe oti ko da lara, o ni bo tile je pe opo awon oti lo wa nita lasiko yi, tawon eeyan n mu, to je pe kaka ko se ara loore, akoba lo n fa fun ilera ara, to si n so awon ni ilera pipe di alainilere pipe, sugbon tawon ti dide lati dena awon aisan to le maa ti ara awon irufe e oti bee jade.

O ni awon oti kan wa to je pe tawon eeyan ba muu, o maa n so eje di omi, idi niyii ti ileese won fi dide lati po awon agbo kan papo to je tawon eeyan ba muu tan, yoo se ara won loore.

Okunrin naa tesiwaju pe idi pataki tawon fi pinu lati se oti Bajinatu jade ni pe oti lawon eeyan n mu ju lasiko yi, sugbon tawon wo o pe won ko gbodo maa mu oti lasan, bi won ba se n mu oti, bee naa ni ki won maa mu agbo naa, nitori pe awon mo nkan tawon omo Naijiria n fe lasiko yii.

Alaaji Kazeem so pe bo tile je pe Oti Seakam Bitters lawon fi bere nigba tawon da ileese Seakam Global Resources sile, tawon si tun ti se opolopo oti bii, Koro Bitters jade, sibe awon si tun lawon oti, paapaa oti waini (wine) tileese naa n pinu lati gbe jade ki odun yi too pari.

O lawon fe kawon eeyan maa mu agbo (Herbal Products) lorisirisi ona nitori to n se ara lore. 

Nigba to n soro lori ayeye ikojade oti tuntun, Bajinatu naa lojo ayajo ololufe, iyen ojo Falentaini (Valentine Day), ojo kerinla osu keji to m bo lona, eyi ti won fe e se nipinle Ogun, o ni orisirisi eto arambara lawon ti la sile fawon alagbata won lati je anfaani lopo yanturu.

Alase Seakam je ko di mi mo pe gbogbo eto lo ti fe e pari bayii fun ti ayeye ikojade oti tuntun tawon eeyan tun n gba ti e lasiko yi, iyen Bajinatu (Poka) to tun je oti ti won fi agbo (Herbal Products) se, eyi ti won lo n fo eje mo toni-toni, to si tun maa n mu egungun ara dide bo se to ati bo se ye.

O lawon ti se ikojade oti naa ni Ikorodu lodun to koja, sibe awon tun fe e se ikojade min in lara oto fawon eeyan lati je anfaani, ati pe gbongan ayeye Ara to wa ni Mowe/Ibafo lo ti maa waye.

AWIKONKO gbo pe ipinle Ogun ni won tonn ta oti Bajinatu laarin awon ipinle merindinlogoji (36 states), tawon eeyan si ti n jeri si ise to n se lara, ko da a, ti ajo NAFDAC tun fi onte luu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI