Epe
rabande rabande lawon eeyan to gbo nipa okunrin kan Andrew Koju, ti won loo lu
omo e kan soso tiyawo e bi fun un pa lojo Aiku Sande to koja lo lohun n gbe
odaju abiyamo naa se latari iwa owu to ni siyawo e.
Abule
Ayedere to wa nitosi Obada Oko nipinle Ogun la gbo pe isele naa ti waye nigba
ti won so pe Andrew yi omo naa, Precious Koku ti won lomo osu mefa ni lorun titi
to fi ku.
Ohun
ta a gbo ni pe iyawo Andrew, Arabinrin Omowumi Teleda lo gba tesan olopaa
Adigbe niluu Abeokuta lo lati loo foro naa to won leti wi pe oko oun pa omo kan
soso toun bi fun un.
AWIKONKO
gbo pe inu ile ni Andrew ati Omowumi wa nibi ti won ti n ba Precioua sere, ati
pe won sese jeun tan lojo naa ni, ko too di pe omo ti Omowumi bi sodo eni to n
fe tele lo ranse pe wi pe oun fe e ri, ati pe oro naa se pataki, lo je ki
Omowumi tete gbera lati loo.
Iyalenu
lo je nigba ti Omowumi maa fi pada dele, oku omo e, Precious lo ba nile, lai je
pe omo naa n saisan tele gege bi a se gbo, ati pe Andrew ti sa kuro nile ki
asiri e maa tu sita wi pe oun lo pa a.
Lesekese
la gbo pe Omowumi ti figbe ta sawon araa abule wi pe ki won gba oun lowo oko oun
nitori to ti seku pa omo kan soso toun bi fun un, ati pe nitori kasiri e ma baa
tu lo se sa jade kuro nile.
Nibe
lawon toro naa soju won ti so pe ko ni suuru digba toko e maa fi de lati beere
boya looto lo seku pa omo naa ti won so pe ko si nkan to se.
Nigba
ti Andrew maa pada de, nise la gbo pe o seni eni ti ko mo nkankan, sugbon
tiyawo e so pe ko sese maa so pe oun maa seku pa omo naa lojo kan to ba fi
gbero lati foun sile loo ba elomin.
Awon
agbaagba ni won ni ki won muu lo sodo awon olopaa, ti won si muu lo tesan
olopaa to wa ni Adigbe lati foro e to won leti, nibi to ti pada jewo pe looto
ni, ati pe oun ko ni le da omo naa to b iyawo oun ba foun sile loo ba okunrin
min in paapaa eni to n fe tele.
Bo
tile je pe Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti tare e sodo eka ileese won to n ri
soro apaayan, sibe o seleri wi pe dandan ni ko foju bale ejo labe ofin.
No comments:
Post a Comment