Titi di bi e ti n ka iroyin yi, ko tii seni to le so pato ibi ti wahala to sese ruwe ninu egbe oselu Labour (Labour Party), eka tipinle Ogun yoo yori si lori bi alaga se di meji lojiji, tawon alaga mejeeji si n so pe isokan ati ilosiwaju egbe lawon n wa.
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, a gbo pe lati ma je ki awon oloselu kan ti won n pinu lati gba egbe naa mo awon to n sakoso e lowo lo je ki won pinu lati yan alaga ti yoo maa tuko e fun imurasile idibo odun 2019 to n bo lona.
Iroyin kan to lo kaakiri orileede yi lose to koja pe Onarebu Ladi Adebutu to n soju ekun Ijebu nile igbimo asofin kekere niluu Abuja fe e gba isakoso egbe naa latari wahala to n sele ninu egbe oselu PDP to wa.
Lesekese la si ti gbo pe aheso lasan ti ko lese nile ni, ati pe awon kan ni won fe e ba egbe naa je lati tako ipinu won lori idibo odun 2019 nipinle Ogun.
Eyi lo fa a ti egbe naa fi pinu lati yan alaga, sugbon ti oro alaga ti won fe e yan naa si da awuyewuye sile laarin won, to di pe egbe naa pin sona meji.
A gbo pe awon apa kan ninu egbe naa lo fara mo Oloye Biodun Owolabi lati di alaga won, nigba tawon apa keji fara mo Komureedi Abayomi Arabambi gege bi alaga won.
Nibi ipade gbogboogbo tipinle ti won se ni ileese egbe naa to wa ni Adatan niluu Abeokuta la gbo pe awon apa kan ti yan Oloye Owolabi gege bi alaga egbe naa, tawon apa keji si yan Komureedi Arabambi nibi ipade bo n kele ti won se ni oteeli kan ta a foruko bo lasiri lagbegbe Kuto niluu Abeokuta bakan naa.
Iroyin to te wa lowo je ko ye wa pe awon otelemuye, iyen Department of State Security (DSS) wa nibi ipade mejeeji lati daabo bo awon omo egbe naa, ki won si le ri bi n kan se n lo sii, ati pe ipade ti won se ni oteeli nibi ti won ti yan Arabambi nikan lawon osise eleto idibo, INEC yoju si.
Nigba to bawon oniroyin soro, Oloye Owolabi so pe ipinu oun gege bi alaga egbe naa ni lati mu egbe oselu Labour pada bo sipo to ye ko wa, ati lati rii pe awon gba agbara kuro lowo egbe oselu All Progressives Congress, APC lodun 2019.
O so pe ko si aaye fun ijoba adase mo nitori pe se loun yoo je kawon omo egbe mo bo ba se n lo ninu egbe naa, toun ko si bii fi nkan pamo fun won.
Ninu oro ti e, Arabambi so pe ko si nkan meji to je oun logun bi ko se lati mu isokan ba egbe naa, ati lati gba ipinle Ogun kuro lowo egbe oselu APC.
O so pe inu gbese nla ni ijoba Amosun ti ko ipinle Ogun si nitori pe igbese ti ko din ni N430billion ni Amosun ti je sile to si je pe odun marundinlaadorin (65) lawon omo ipinle Ogun yoo fi san an.
No comments:
Post a Comment