Abanije Lawon To Fe e Ba Oga Wa Loruko Je - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 22, 2018

Abanije Lawon To Fe e Ba Oga Wa Loruko Je

Igbimo majeobaje ajo ile awon omo alailobii, (The Alumni Association of Stephens Children Home) to wa ladugbo Obantoko niluu Abeokuta, ipinle Ogun ti so pe iro para to jinna si otito oro ni esun ifipabanilopo ti won fi kan adari ileewe naa, iyen Ogbeni Isaac Oluwole Newton-Wusu, ati pe awon alatako ti won ko feran okunrin naa lo wa nidi iroyin ibaniloruko je naa.

Aare egbe naa, Ogbeni Thoma Davou Gyang lo soro naa lai pe yi lasiko to n bawon oniroyin soro ninu gbongan ayeye awon oniroyin to wa ni Iwe-Irohin, Abeokuta, nibe lo ti so pe iroyin ibaniloruko je patapata ni won n gbe kaakiri.

Gyang so pe awon kan ninu egbe naa ti won ko feran alakoso won yi, Newton-Wusu ni won lo ko ara won jo lati wa gbogbo ona ti won le gba lati je ki won yo okunrin naa gege bi alakoso, ki won si le yan eni tawon fe sibe.

Okunrin naa so pe nigba ti won bere oro naa, ni won sare gba olu ileese olopaa ipinle Ogun to wa ni Eleweran lo lati loo fi to won leti, leyin tawon olopaa si bere ise iwadii won ni won to o mo pe iro ni won wa a pa fawon.

Davou Gyang to siwaju awon igbimo to ku je ko ye wa pe opo awon omo to le ni ogofa (120) ni lawon ti ko ni eko to ye kooro ni Stephen Children Home, ti won si n se daadaa kaakiri awon ile eko giga ti won ran won lo, paapaa lawon ibi ti won tun wa kaakiri agbaye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI