Nise nidunnu subu lu ayo awon ara
oja Ikenne nipinle Ogun nigba ti won ri igbakeji Aare orileede yi, Ojogbon Yemi
Osinbajo nigba to wonu oja naa to won wa, to si tun bawon sere ko too kuro
nibe.
AWIKONKO gbo pe ibi ayeye ojo ibi odun
marundinlogorin (75) ti ojise Olorun Adebanjo ni Osinbajo ti kuro to si pinu
lati loo ki awon eeyan e to ti ri tipe.
Ko seni ti Osinbajo ko ba soro
lakoko naa, nitori pe terin toyaya ni won fi pade e, toun naa si tun beere lowo
won bi oja won se n lo si.
Nibe ni Osinbajo ti seleri fun won
pe ki won tubo nisuuru fun ijoba yi nitori pe ijoba to n fe ti araalu ni.
Lara awon ti won tele Osinbajo ni
Ogbeni Babatunde Irukera to je akowe egbe eleto aabo kan, iyen Consumer Protection Council, CPC ati alaga ijoba ibile
Ikenne Ogbeni Akinsanya Rotimi Fatai.
No comments:
Post a Comment