NUJ ipinle Ogun fe e se idanilekoo ara oto fawon oniroyin ori ero ayelujara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 13, 2017

NUJ ipinle Ogun fe e se idanilekoo ara oto fawon oniroyin ori ero ayelujara

Ko si iroyin meji to n lo kaakiri orileede Naijiria bayii bi ko se ti idanilekoo ara oto ti egbe akoroyin nipinle Ogun, iyen Nigeria Union of Journalist fe e se pelu egbe awon oniroyin ori ero ayelujara, iyen National Association of Nigerian Bloggers, NANB lojo Aje Monde to m bo, ojo mejidinlogun osu yii.

Ojo Tusde ana ni ipinu naa waye leyin tawon igbimo isakoso fidihe fegbe NANB naa loo se abewo si alaga akoroyin nipinle Ogun, Komureedi Wole Sokunbi ni ofiisi e to wa ninu ogba ileese awon oniroyin to wa ni Oke-Ilewo niluu Abeokuta.

Lakoko abewo naa ni alaga naa, Sokunbi ti gboriyin fawon igbimo fidihe egbe naa, to si so pe o ti pe toun ti n fe e ri won, ki ajosepo to dara le wa laarin egbe mejeeji.

Sokunbi je ko di mimo pe ki ajosepo to dan moran to le wa daadaa laarin won, a fi ki won gbe eto idanilekoo nla kale fawon omo egbe naa, ki won si le tubo jo o so asoyepo lori ona ti won yoo se jo maa sise papo.

Akori idanilekoo naa ni won pe ni "The New Media: "Bloggers, a viable tools to Nation Building", iyen ni pe iroyin ori ero ayelujara, irinse pataki lati mu idagbasoke ba orileede.

Inu gbongan awon oniroyin to wa niluu Abeokuta ni idanilekoo naa yoo ti waye laago kan osan ojo naa, nibi ti awon agbaagba oniroyin to fi mo awon Ojogbon leka ise ijoba kaakiri yoo ti wa nikale.

Ninu oro ti e, alaga fidihe fegbe naa, Komureedi Solanke Ayomideji Taiwo dupe gidigidi lowo alaga naa fun bo se gbawon lalejo lai ro tele, to si tun gbawon lamoran pelu ileri iranlowo to so pe egbe NUJ naa yoo se fun won.

Lakoko abewo naa
Solanke so pe o ti pe tawon ti n pinu lati da egbe naa sile, sugbon tawon wo o pe asiko yi gan an lo daraju lati le je kawon oniroyin ori ero ayelujara, iyen Bloggers wa labe aburada (umbrella) kan soso.

O so pe kii se ipinle Ogun nikan ni egbe naa wa fun, kaakiri orileede Naijiria ni, tawon eeyan yoo si dide fun idanilekoo naa. Bee lo so pe igbese ti bere lati rii pe ajosepo to dan monran wa laarin egbe mejeeji.

Lakotan, Solanke ro gbogbo awon oniroyin ori ero ayelujara lati dide mo egbe naa, nitori pe awon gan an ni agbara wa lowo e lati tun orileede yi se nipa awon iroyin ti won n gbe jade.

Fun alaye lekunrere nipa idanilekoo naa, e pe Komureedi Ayomideji sori numba e yii; 08139267127.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI