Oludije sipo gomina nipinle Ogun lodun 2015 to tun je oludasile ajo Paseda Lagacy Foundation, Omoba Olarotimi Paseda ti pariwo sita lojo Aiku Sande ana, iyen ojo kewaa osu kejila wi pe oun kii se oniwaasu, sugbon toun je wooli Olorun.
Paseda soro yi lakoko to n bawon eeyan soro nibi isoji ita gbangba oni Sande meta nipinle Ogun, eyi to n sagbateru e lowolowo lati fi tako oro to n lo labele wi pe igba wo lo di oluso aguntan.
Paseda so pe omo kekere loun wa nigba toun di Wooli, ati pe oun ko dede di Wooli, to si je pe oun maa n reran sawon nkan to maa sele lojo iwaju.
O so pe bo tile je pe onigbagbo ni baba to bi oun sugbon ti kii lo si soosi, ati pe ijo Anglican n’iya to bi oun n lo. O ni mama kan lo mu oun lo si ijo sele nigba toun wa ni kekere, nibe si ni ise iranse oun ti bere.
Olarotimi so pe nigba toun koko wonu ijo sele lojo naa lohun, odo awon akorin loun loo jokoo si, nigba ti won si bere ise iranse, nibe loun rii mo, nitori pe tie mi ti gbe oun. O so pe ojo keta loun to o mo nnkan to n sele, toun si bere sii so pe ki lo se oun, ati pe nibo loun wa.
Oludije sipo gomina yi tun je ko di mimo pe awon to wa nibe ni won nkan to sele foun, latigba naa ni won si ti so fawon obi oun pe won ko gbodo ya oun kuro ninu ijo sele ayafi toun ba finu-fido kuro nibe, bee lo so pe iyalenu lo je foun atawon obi oun.
Okunrin naa tesiwaju pe nibe loun ti bere sii wo aso funfun, nitori topo awon eeyan ti n ro pe o ni nkan toun fi se. O je ko di mimo pe oun ko le saigboran si ise Olorun, nitori e loun se n wo awso funfun, ati pe oun ko le maa wo aso sele kaakiri, lo je koun maa ran orisirisi aso to je funfun.
Siwaju sii, o je kawon eeyan mo pe ijo sele loun ti ri igbala ati owo toun ni lonii, nitori to so pe eni kan ni Olorun lo lati ran oun lo silu Oyinbo, iyen England nibi toun ti loo kawe.
Paseda so pe nigba toun de be ni Olorun lo enikan foun, to fun oun ni ile olowo nla, toun si lo opolo oun lati tun ile naa se. o so pe oun so ile naa di meji toun si tun gba ase lowo eni to fun oun. O ni nigba toun maa tai le naa, ogun dola (20 dollars) loun ta, ti owo naa si ka oun laya.
Latigba naa lo ti so pe aseyori oun ti bere, toun si bere sii fi oun naa se nkan rere, ko too di pe oun pinu lati wa a dupo gomina ipinle Ogun.
Nigba to n soro lori isoji ita gbangba to n sagbateru e lowolowo, Paseda so pe oun kii deede se nkan lai gbo ohun Olorun. O so pe Olorun lo so foun koun gbe isoju nla naa kale, toun ko si gbodo ko oro si ohun Olorun.
Lakotan, Omoba Paseda gbawon omo Naijiria, paapaa awon omo ipinle Ogun lamoran wi pe ki won tubo ni suuru, nitori ti Olorun ti so pe iyanu nla si maa sele, to si je pe lai pe yi lo maa sele.
Bakan naa lo so pe isoji ita gbangba naa kii se ti oro oselu rara, ati pe fun imupadabosipo lo wa fun.
AWIKONKO gbo pe Ilu Ijebu Ode ni won yoo ti kadi isoji naa lojo Aiku Sande to n bo, iyen ojo ketadinlogun osu yi.
No comments:
Post a Comment