Johnson Akinpelu gbami eye idalola - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 21, 2017

Johnson Akinpelu gbami eye idalola

Nise ni idunnu subu lu ayo Ogbeni Johnson Akinpelu to je asojukoroyin ileese iwe iroyin Alaroye nipinle Ogun lonii ojo Tosde, ojo kokanlelogun osu kejila odun 2017 nigba ti egbe Fijilante VGN to je ti Komanda Alaaji Aliu Sokoto fun un lami eye idalola gege bi oniroyin to jara mose.

Gbongan ayeye Dorf Royal to wa ni adojuko ileese redio RockCity to wa ni Asero, Abeokuta ni ayeye nla naa ti waye nibi ti awon oniroyin egbe e ti ba a yo ayo naa.

AWIKONKO gbo pe kii se pe won dee de fun Johnson Akinpelu to tun je oludasile ati olootu iroyin ori ero ayelujara, iyen BOSERI lami eye idalola naa bi ko se pe leyin opolopo iwadii nipa awon oniroyin ati asojukoroyin nipinle Ogun ni won sakiyesi wi pe ko se ni to tun le gbami eye naa bi ko se okunrin naa.

Ayeye naa tawon agbaagba egbe Fijilante kaakiri ile adulawo ti peju sibe la gbo pe won se e lati fi bu ola ati iyi fawon to ti sise takuntakun lawujo paapaa awon to ti ko ipa to jo ju fun egbe Fijilante VGN naa.

Nkan to je ki ami eye naa tun je eyi to ya ni lenu ni bi Johnson tun se gba emi eye loruko ileewe World Information Agent to n gbe iwe iroyin ALAROYE ati AKEDE AGBAYE jade gege bi ileese to n gbe ede asa ati ise Yoruba laruge.

Nigba to n b'AWIKONKO soro, Johnson Akinpelu so pe bo tile je pe eyi kii se ami eye akoko toun yoo gba, sugbon toun gba ami eye yi lati fi dupe lowo Olorun to foun lanfaani lati gba a.

O ni kii se pe oun ro o ti pe oun yoo gbami eye, sugbon lai pe yi ni won pe oun pe oun to si ami eye, ti won si wa a ba oun ni ofiisi oun nibi ti won ti salaye bo se je foun.

Akinpelu wa a seleri wi pe ajosepo to dan monran ni yoo wa laarin oun ati egbe Fijilante VGN naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI