Egbe odo ile Yoruba fe e sepade lori atunto orileede Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 11, 2017

Egbe odo ile Yoruba fe e sepade lori atunto orileede Naijiria

Gbogbo eto lo ti fe e pari bayii lori ipade atunto orileede yii, ti egbe odo ile Yoruba, iyen Yoruba Youth Council (YYC) kaakiri agbaye fe e se niluu Ibadan lojo kokandinlogun osu yi, iyen 19th December, 2017.

Alaafin Oyo
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo lai pe yi latodo alaga egbe naa nipinle Ogun, Komureedi Daniel Sodeinde se so, o ni gbongan House of Chief Parliament to wa nile ise awon osise ijoba ipinle Oyo, iyen Secretariat to wa niluu Ibadan nipade nla naa ti fe e waye.

Sodeinde je ko di mimo pe alaga igbimo ti won yan fun ipade gbogboogbo naa, Komureedi Femi Awogboro ti so pe awon eeyan jankan-jankan to je omo bibi ile Yoruba lo maa wa nibi ayeye naa latari awon eto ati ilana ti won la kale.

Bee lo so pe okan lara awon ogbontarigi omo ile Yoruba to ti kopa ribiribi lori idagbasoke Yoruba, Ogbeni Opeyemi Agbaje lo maa dawon eeyan lekoo lori akori ipade naa ti won pe ni "NIGERIA PRE & POST INDEPENDENCE: The Critical Paradigm of Yoruba Youth as Motivator of Regional Restructuring".

AWIKONKO gbo pe Aare egbe naa, Komureedi Eric Oluwole pelu awon igbimo egbe naa ti gba iwe ase latodo awon agbaagba ile Yoruba, paapaa Gomina Abiola Ajimole tipinle Oyo lati le je ki ayeye naa larinrin, ko si je itewogba latodo awon omo ile Yoruba tooto.

Kaadi ipe
A tun gbo pe Gomina Ajimobi ni yoo gbawon Oba ile Yoruba bii Alaafin Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi; Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi Enitan, to fi mo Aare Ona Kakanfo tuntun, Otunba Gani Adams ti yoo je gege bi alejo pataki ojo naa lalejo.

Aago mokanla aaro la gbo pe won yoo tepepe eto naa lai lo aago ile adulawo, iyen African time, bakan naa ni won wa a rawo ebe sawon omo ile Yoruba lapapo kaakiri orileede yi ati loke okun lati wa a da si koko pataki ti won fe e soro le lori lojo naa.

Won si seleri pe gbogbo oro ati edun okan awon eeyan ni won yoo dahun lojo naa, ti won yoo si sise takuntakun lori e lati rii pe ile Yoruba pada di okan soso nipa ife ati alaafia.

A tun gbo pe eto aabo to pe ye lo maa wa fun gbogbo awon eeyan lojo naa latari bi won ti se fiwe ranse sawon ileese eleto aabo kaakiri orileede yi, paapaa nipinle Oyo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI