Pupo ninu awon odo atawon agbaagba lorileede
Naijiria ni won ti fehonu won han lonii kaakiri ipinle to wa lorileede yi latari
ona tawon osise eka olopaa ti won pe ni SARS n gba sise won, eyi ti won so pe
ko bojumu to.
Ni nnkan bi ose meji seyin ni enikan gbe oro
naa sori ero ayelujara wi pe ki won yo eka ileese olopaa naa, iyen Special
Anti-Robbery Squad (SARS) kuro nitori wi pe won ko je kawon eeyan gbadun, ti
won si n se won nisekuse.
AWIKONKO gbo pe latigba naa lawon omo
orileede yi ti gbe oro naa pari, tonikalu sib ere sii so isoro ti won ti ba
pade lodo awon ti won n pe ni SARS yi, ko da, ti won tun fi orisiri fidio sita
lati le je kijoba apapo tete gbe igbese lee lori.
Ilu Abuja ni iwode ipolongo ifehonu han naa
ti bere ni gbagede Unity Fountain; ti won si tun se e lawon ipinle bii Eko,
iyen ni Gani Fawehin Park ati Ojota. Lara awon ipinle ti won tun ti se iwode
naa ni Jos sati Port-Harcourt.
Lara awon ipinle ti won yoo tun ti se iwode
ifehonu han alaafia naa ni Kaduna, Ibadan, Awka ati bee bee lo.
Eyi lawon aworan ti won fi se iwode naa.
No comments:
Post a Comment