Akarigbo tuntun fee gbade lojo Tosde ose yi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 5, 2017

Akarigbo tuntun fee gbade lojo Tosde ose yi

Gbogbo eto lo ti pari bayii, ti ese ko si ni fe e gba ero ni papa isere Gateway Intermatinal to wa niluu Sagamu nibi ayeye igbade Akarigbo tile Remo tuntun, iyen Oba Babatunde Adewale Ajayii.

Gege b'AWIKONKO se gbo, ojo Tosde ose yi, iyen ojo keje ni ayeye nla naa yoo waye nibi ti won yoo ti gbalejo igbakeji Aare orileede yi, Ojogbon Yemi Osinbajo.

Ayeye olojo merin naa la gbo pe orisirisi eto olokan-o-jokan ni won ti la kale, lara e ni ti idije ere boolu alafesegba, idije ere sisa ati bee bee lo.

Be o ba gbagbe, ojo kokanlelogbon osu kejo ni won dibo yan Oba Adewale Ajayi gege bi Akarigbo tile Remo, to si je pe latigba naa lo ti wo ipebi, to si pari e lai pe yi.

Nigba to n bawon oniroyin soro lose to koja, alaga igbimo eto ayeye naa, Asiwaju Solomon Onafowokan so pe Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ni yoo gbe Ade le Oba Adewale Ajayii lori lojo naa, to si tun so pe aabo to peye nijoba ti sagbateru e nitori awon eeyan jankanjankan to n bo.

AWIKONKO gbo pe awon Oba alaye bii Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi; Sultan tiluu Sokoto, Sa'adu Abubakar; Emir tiluu Kano, Alaaji Sanusi Lamido Sanusi; Obi tiluu Onitsha, Igwe Alfred Ashebe atawon min in ni yoo peju sibe lati ba Kabiyesi yo.


Alaga ayeye naa wa a ro gbogbo awon omo ile Remo jakejado orileede yi ati loke okun lati wa a ba Oba tuntun naa sajoyo lojo naa pelu ileri aabo to peye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI