Kii
tun un se iroyin tuntun mo pe Dokita Alex Ifeanyichukwu Ekwueme to je igbakeji
Aare eleekeji lorileede Naijiria ti jade laye ni nkan bi aabo mewaa ale ojo
Aiku Sande to koja yi.
Sugbon
nkan to n ya awon eeyan lenu lori iku baba agba naa bi won se so pe osibitu kan
niluu London lo ku si leyin aisan kan ti won lo ti n ba a finra lati osu kewaa
odun yi, to si je pe aisan naa lo pada seku pa a.
Bo
tile je pe bi iroyin naa se ti n jade sita, tawon eeyan ko koko gbagbo, to si
pada di otito leyin ti aburo baba agba naa, Igwe Laz Ekwueme fi atejade sita
lojo Aje Monde ana wi pe awon ti padanu baba naa.
Latigba
naa la gbo pe won ti gbe e lo sile iwosan Memfys Neurosurgery, nibi to wa fun ose meji gbako
ko to o di pe won gbe e lo siluu London lojo kejila osu yi nigba ti agbara won
ko ka mo nibe.
Bakan naa
la tun gbo pe nigba ti won sayewo kan fun oloogbe naa ni won to o mo pe o ni
aisan okan, iyen chest pain, to tun je nkan to sokunfa ko tete ku.
No comments:
Post a Comment