Bo
tile je orisirisi lawon araalu to gbo soro iku akobi Oloye Bola Tinubu to je
asiwaju agbegbe oselu APC lorileeede yii n so nipa nnkan to sokun fa iku Jide
Tinubu, sibe ohun ta a gbo ni pe aisan okan (heart attack) lo seku pa a lojiji.
Asiwaju Tinubu |
Gege
bii iroyin to te AWIKONKO lowo, a gbo pe ni nnkan bii ago mesan an ale ojo
Isegun Tusde to koja yi, iyen ojo kojanlelogbon ni won so pe Jide to je omodun
metalelogoji deede subu lule, to si gbabe ku.
Ere
la gbo pe awon toro naa soju won koko pe e, nitori ti won so pe won si n bawon
ti won jo wa papo dapara lowo, ko too di pe o sare di igba aya e mu, to si subu
lule.
Lesekese
la gbo pe won ti sare gbe e lo si osibitu kan to wa ni Lagos Island, sugbon
nigba ti won maa fi de be, akuko ti ko leyin omokunrin naa, ti won si so fun
won ni osibitu pe oku ni won gbe wa.
Nibi
ipade awon oloye egbe oselu APC ti won se nilu Abuja la gbo pe baba e, Ahmed
Tinubu wa, ti won ko si gbe iroyin naa sii leti, oku oru la gbo pe won se oro
iku e, sugbon nigba to pada de ilu Eko lojo Wesde ni won sese soro naa jade
sita.
Awon
to sunmo ebi Tinubu to je ka mo bo se n lo so pe nise lawon eeyan sare di
Tinubu mu, nitori pe die lo ku ko subu lule nigba to gbo iroyin akobi omo e
naa, eni ti won so pe o feran lati maa pa awon eeyan lerin.
Titi
di bi a se sakojopo iroyin yi tan, mosuari osibitu kan ta a foruko bo lasiri la
gbo pe won gboku naa si, lati se ipalemo bi won yoo se sinku Jide Tinubu to je
okan lara awon agbejoro lorileeede Naijiria.
Bakan
naa la gbo pe opo awon eeyan ja-nkan-ja-nkan lorileeede yi ati kaakiri agbaye,
to fi mo awon oloselu atawon abanikedun lo ti bere sii lo ki Oloye Bola Tinubu
nile, lati ba a kedun, bee lawon ti ko si nitosi naa n fi ateranse ibanikedun
ranse si agba oloselu naa.
Lara
awon to ti ba idile Tinubu kedun ni Aare Muhammadu Buhari, Ojogbon Yemi
Osinbajo, Gomina Orton, Ogbeni Femi Adesina, Oloye Femi Fani-Kayode, Otunba
Gbenga Daniel, Gomina Ibikunle Amosun, Otunba Rotimi Paseda, Gbogbo ile igbimo asofin agba lorileede yi, Gomina Abiola
Ajimobi atawon min in.
No comments:
Post a Comment