Pelu
bi nnkan se n lo nileewe giga gbogbonise Moshood Abiola, MAPOLY ti won tun ti
so di Moshood Abiola University of Technology, MAUSTECH bayii, afaimo ni kawon
oluko agba atawon osise patapata ma dana oro fun Adele oga agba (Acting
Rector), Ogbeni Sulaiman Ayodeji Tella ti gomina Ibikunle Amosun tipinle Ogun
loun yan, leyin to da oga gba nibe tele, Ojogbon Oludele Itiola duro ni
tipatipa.
Ko
si n kan meji to fa a bi ko se bi won se so pe okunrin naa ko niwe eri to kun
oju osuwon lati di oga agba nileewe naa, ati pe ko seni to le so lato ile to ti
jade, ti won si tun so pe etanu ni Gomina Amosun fi yan an sibe latari wahala
ti agbarijo awon osise nileewe Poly, iyen ASUP n ba ijoba fa lori ona ti won
gba da MAUSTECH naa sile.
Be
o ba gbagbe, ojo keta osu mewaa to koja yii ni Gomina Amosun ni ki Ojogbon
Otiola lo jokoo ifeyinti (terminal leave) sile e, ki Ogbeni Tella si lo o ropo
e digba ti wahala naa yoo fi wa sile, o si seese ko je pe oun ni won yoo maa lo
lo.
Latigba
naa lawon osise atawon agbaagba nileewe poli naa ti n beere lowo okunrin naa wi
pe ko ko awon iwe eri to ni sile ati itan mipa igbesi aye e sile, kawon le mo
boya o kaju eni ti le fi se aga agba le won lori.
Fawon
to ba mo ileewe MAPOLY naa daadaa, yoo mo pe ko din ni marundinlogota (55) lawon
to niwe eri PhD nibe, lai ka awon to sese gnoye PhD ni fasiti FUNAAB lose
meta seyin nibi ayeye ikekoo jade (convocation) ti won se.
Gege
bi iroyin to te AWIKONKO lowo lati nnkan bi ose meji seyin se so, a gbo pe
oga agba ileewe girama kan ni Ogbeni Tella tele, ko too di pe Gomina Amosun lo
pe e, ti won si so pe okunrin naa ko niwe eri Masters Degree.
AWIKONKO gbo pe gbogbo akitiyan awon osise lati je ki okunrin naa ko awon iwe eri
to ni sile lo n ja si pabo titi dasiko ta a sakojopo Iroyin yi tan nitori ti
won so pe se lo n fi ojo kun ojo fun won, ati pe kii se gbogbo igba lo n yoju
sileewe naa nitori e.
Lati
fidi oro naa mule, AWIKONKO gbiyanju lati ba agbenuso ileewe naa, Ogbeni
Sulaiman Adebiyi soro lo ja si pabo, ti ko si tun da atejise wa pada titi
dasiko taa sakojopo iroyin yi tan.
Bee
la gbo pe awon osise naa tun ti gun le iyanselodi ni tipatipa, bo tile je pe
oni ojo Aje Monde ni won so pe idanwo to ti ye ko bere lati bi osu meji seyin
bere, sugbon nitori pe Gomina Amosun ko tii dawon lohun nnkan ti won n fe lati
odo ijoba lo fa a.
Okan lara
awon oluko to b'AWIKONKO soro laaro ojo Satide to koja yii, eni taa foruko
bo lasiri so pe awon ko tii mo igba tawon yoo pada wole, nitori pe bi Gomina
Amosun ko ba dawon lohun, ko si ise ati pe lara nnkan tawon n fe ni pe ki
Amosun je kawon si maa lo Abeokuta digba ti won yoo pari Ipokia.
Won
ni agidi e lo fa a to fi ba eto Eko je nipinle Ogun, to si n so pe obitibiti
owo lawon n na lori eto Eko, sugbon tawon eeyan ko ri koko e.
No comments:
Post a Comment