- IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 8, 2017


Wahala be sile nitori isinku birikila ni Sagamu
Gbenga Oladipupo

Nise loro di boo lo o yago lojo Isegun Tusde to koja yi nigba tawon odo kan bere wahala pelu awon eso to n so ogba ipebi Akarigbo tile Remo to wa ladugbo Ita Oba niluu Sagamu, ipinle Ogun.

Bo tile je pe orisirisi awuyewuye la gbo nipa nkan to sokunfa wahala tawon, nitori bawon kan se n so pe awon SARS atawon omo Yahoo ni won koju ija sira won, tawon eeyan meji si padanu emi won.

Sugbon iroyin to te AWIKONKO lowo je ko ye wa pe iroyin otooto ni, ati pe ojo Aje Monde lawon omo Yahoo atawon olopaa SARS ti koju ija sira won, leyin ti won so pe awon olopaa seku pa awon odomobinrin meji kan, ti enikan si farapa.

Sugbon lojo Tusde naa la gbo pe awon omo egbe kolekole birikila n gbiyanju lati sayeye ikeyin fun okan lara won to doloogbe, ti won si n gbiyanju lati gbe oku e koja legbe ile Ipebi ti Kabiyesi ti won sese yan wa, to ti n se Ipebi e lowo.

Alariya Oodua gbo pe awon eso to n so ile Ipebi ati Kabiyesi naa lo dawon duro wi pe eewo ni ki won gbe oku koja lakoko ti Kabiyesi ba n se Ipebi e lowo, ati pe ki won loo gba ona min in to jinna sibe.

Odi la gbo pe oro awon eso yi bo si fawon omo egbe birikila naa, ti won si so o dija mo awon eso naa lowo, ko too di pe oro di boo lo o yago lona, tawon to wa ladugbo naa si sa asala fun emi ara won.

Nigba toro naa si awon araadugbo ni won loo fi to awon olopaa leti, ko da, ta a gbo pe awon olopaa to wa nikorita meta aafin Oba naa fese fee, ko too di pe awon olopaa ekun Sagamu de be.

Nnkan to tun je koro naa pariwo repete ni ba a se gbo ti won so pe awon olopaa naa ro pe awon omo Yahoo ni won tun wa fa wahala nibe, ti won si da ibon bole to di olori di ori e mu, tolomo ko mo omo won mo, bi ogun Idahomi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI