Wahala be sile nitori isinku birikila ni Sagamu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 13, 2017

Wahala be sile nitori isinku birikila ni Sagamu

Nise loro di boo lo o yago lojo Isegun Tusde to koja yi nigba tawon odo kan bere wahala pelu awon eso to n so ogba ipebi Akarigbo tile Remo to wa ladugbo Ita Oba niluu Sagamu, ipinle Ogun.

Bo tile je pe orisirisi awuyewuye la gbo nipa nkan to sokunfa wahala tawon, nitori bawon kan se n so pe awon SARS atawon omo Yahoo ni won koju ija sira won, tawon eeyan meji si padanu emi won.

Sugbon iroyin to te AWIKONKO lowo je ko ye wa pe iroyin otooto ni, ati pe ojo Aje Monde lawon omo Yahoo atawon olopaa SARS ti koju ija sira won, leyin ti won so pe awon olopaa seku pa awon odomobinrin meji kan, ti enikan si farapa yannayanna.

Sugbon lojo Tusde naa la gbo pe awon omo egbe kolekole birikila n gbiyanju lati sayeye ikeyin fun okan lara won to doloogbe, ti won si n gbiyanju lati gbe oku e koja legbe ile Ipebi ti Kabiyesi ti won sese yan wa, to ti n se Ipebi e lowo.

AWIKONKO gbo pe awon eso to n so ile Ipebi ati Kabiyesi naa lo dawon duro wi pe eewo ni ki won gbe oku koja legbe ile Ipebi paapaa lakoko ti Kabiyesi ba n se Ipebi e lowo, ati pe ki won loo gba ona min in to jinna sibe.

Odi la gbo pe oro tawon eso yi so kale bo si fawon omo egbe birikila naa, ti won si so o dija mo awon eso naa lowo, ko too di pe oro di boo lo o yago lona, tawon to wa ladugbo naa si sa asala fun emi ara won.

Nigba toro naa si pariwo n la lawon araadugbo loo fi to awon olopaa leti, ko da, ta a gbo pe awon olopaa to wa nikorita meta aafin Oba naa fese fee, ko too di pe awon olopaa ekun Sagamu de be.

Nnkan to tun je koro naa pariwo repete ni ba a se gbo ti won so pe awon olopaa naa ro pe awon omo Yahoo ni won tun wa fa wahala nibe, ti won si da ibon bole to di olori di ori e mu, tolomo ko mo omo won mo, bi ogun Idahomi.

Leyin o reyin la gbo pe won yanju e, ti won si ko awon kan lo si tesan olopaa lori e.

Lojo Tusde naa la tun gbo pe awon olopaa SARS tun ya wo oteeli kan taa foruko bo lasiri, to je ti iyawo okan lara awon omo ile igbimo asofin ipinle Ogun, ti won si se awon eeyan to wa nibe nisekuse, to fi mo omo ile igbimo asofin naa, Onarebu Olayinka Mafe ti won fo idi ibon mo lori.

Ohun ta a gbo ni pe tirela mokandinlogun lawon SARS naa fi ara won wa lojo naa, ti ko si tii seni to le so pato nipa nkan to sokunfa wahala laarin won titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan.

Lara awon to gbe isele naa si wa leti je ko ye wa pe o ni owo kan tawon omo Yahoo to wa ni Sagamu maa n san fawon SARS sugbon ti won so pe won ko san owo naa fun won mo, ati pe enikan lara awon omo Yahoo yi tuntun sese gba obitibiti owo nla kan ni, tasiri e si tu sawon SARS naa lowo.

Lakoko isele naa la gbo pe awon SARS naa rowo to awon eeyan ti ko din ni ogbon loo si ogba won to wa ni Magbon niluu Abeokuta lati loo tesiwaju ninu ise iwadii won.

Lati fidi isele naa mule, akoroyin wa gbiyanju lati ba Agbenuso fun ileese olopaa, Abimbola Oyeyemi soro lori aago, sugbon ti ko gbe foonu e, ti ko si pe wa pada titi dasiko taa sakojopo iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI